Sell to
Get paid with
Price per Tether
Bíí ó ṣe Le Ta Tether lórí Paxful
Ní Paxful, a ṣe ìrànlọwọ fún àwọn ènìyán láti sunmọ òmìnira ìṣúná owó àti jẹ àwọn ọgá ti ara wọn. Èyí ni ìdí ti ní àfikún sí Bitcoin, o tún lè ta Tether (USDT) tààrà fún àwọn aṣàmúlò tó ju mílíọnù mẹta ní àgbáyé. Pẹlú àwọn sísanwó tí ẹ́síkírò ṣe àtìlẹyìn fún, òmìnira láti ṣètò àwọn òṣùwọn rẹ, àti lórí àwọn ìlànà ìsanwó tí o ju 300 lọ láti yan, Ibi Ìtajà ti agbára àwọn ènìyàn wa jẹ kí o rọrùn fún gbogbo ènìyàn láti jèrè.
Láti bẹrẹ, forúkọsilẹ lórí Paxful tàbí wọlé sí àkántì tí o wà tẹlẹ kí o tẹlé àwọn ìgbésẹ wọnyí:
- Ṣètò ìlànà ìsanwó tí o fẹ jùlọ àti kọ́rẹ́ńsì tí o fẹ kí won fi sanwó.
- Tẹ Wá Àwọn Ìnájà láti wo àtòkọ ti àwọn ìnájà tí ó bá awọn ìbéèrè tí o ṣẹṣẹ tẹ síí mu.
- Nígbàtí o bá ńwo àwọn ìnájà, fiyèsi gbogbo àlàyé. Èyí pẹlú àwọn ìgbayìsí ti àwọn tí olùrajà, wíwà wọn, àti àwọn òṣùwọn tí a dábàá. Ti o kò bá lè ríì ìbáramu tó dára, o lè nígbàgbogbo ṣẹdá ìnájà ti ara rẹláti fa àwọn aṣàmúlò tí ó nífẹ láti ra Tether lórí àwọn àdéhùn rẹ.
- Lọ́gán tí o bá ti ríí ìnájà tí ó fẹ́, tẹ Tà . Kì yóò bẹ̀rẹ̀ òwò síbẹsíbẹ; dípò, ìwọ yóò rí àwọn àdehùn àti Kání ti olùrajà náà.
- Tí o bá gbà pẹlú àwọn àdéhùn náà, tẹ iye tí o fẹ ṣòwò fún àti tẹ Tà Báyì. Èyí yóò bẹrẹ òwò náà àti gbé USDT rẹ sí ìlànà ààbò ẹ́síkírò wa.
- Ṣe àkíyèsí àwọn ìtọ́nísọ́nà olùrajà náà kí o pèsè àlàyé tí o yẹ ní ìtàkurọ̀sọ ojútáyé. Lọgán tí o bá ti gbà owó sisan, o lè fi USDT silẹ lati ẹsíkírò wa sínú wálẹ́ẹ̀tì ti olùrajà, kí o tọjú ẹ̀rí ìsanwó tí gbogbogboo.
- Lẹ́yìn ìṣòwò, nígbàgbogbo ronú láti fi ìjábọ̀ sílẹ lórí olùrajà. Èyí kìí ṣe ìrànlọwọ fún wọn nìkan láti ṣàgbékalẹ̀ ìgbayìsí wọn, ṣùgbọn tún fún àwọn olókòwò mííràn ní ìmọràn ti ẹni tí wọn ń ṣe pẹlú.
Láti ní ìrírí ìdókòwò tí kò ní wàhálà, ka àwọn òfin wa fún títà Bitcoin àti Tether . O tún lè ṣàyẹwò wa ìtọ́sọ́nà sí ṣíṣẹdá àwọn àdéhùn ìfilọ̀ ìnájà tí o dára kí o lè ṣẹdá àwọn ìnájà àwòmáleèlọ fún àwọn olùrajà rẹ.
Níbí ní Paxful, a ní àwọn ìdáwọ́kọ́ tó gbópọn nítorínà o lè ṣe òwò láìléwu nígbàkugbà, níbikíbi. Ṣàwákiri nípasẹ àwọn ẹgbẹẹgbẹrún ti àwọn ìnájà tí ó tọ kí o bẹrẹ títà Tether lónì!