Buy from
Sanwó pẹ̀lú
Price per Bitcoin
Bíí ó ṣe Le Ra Bitcoin lórí Paxful
Ra Bitcoin (BTC) pẹ̀lú oye tó jálẹ̀ jùlọ láti ibikíbi tí o wà. Paxful ń ṣiṣẹ́ lóri òfin ìṣura owó ẹnìkan-sí-ìkejì tó fún ọ ní àyè láti ra BTC ní oye tó kéré tó 10 USD. O lè ràá ní tààrà láti àwọn èyàn bíi tìrẹ - láì sí àwọn bánkì àti ilé iṣẹ́.
Nkan tó dára jùlọ? Kò sí owó iṣẹ́ tí o bá ra BTC lóri Paxful. Èyí túmọ̀ síi pé o lè ra Bitcoin púpọ̀ si pẹ̀lú owó rẹ. Ọpẹ́lọpẹ́ àwọn ìlànà ìsanwó tó fẹ́rẹ̀ tó 400 tó wà ní ìkání náà, o lè yí owó rẹ sí Bitcoin pẹ̀lú wálẹ́ẹ̀tì ayélujára àti ìfowóránṣẹ́ bánkì. O tùn lè fi àwọn kọ́rẹ́nsìkírípítò ìmín ṣòwò bíi Ethereum fún Bitcoin, àbí kí o ta káàdì ẹ̀bùn láti fi gba àgékúrú BTC.
Paxful wà ní àbò tó le jùlọ, ó sì wà lábẹ́ òfin ní ìlú Amẹ́ríkà gẹ́gẹ́ bíi Òwò Oníṣẹ́ Owó. Ibi ìtajà wà lábẹ́ ẹ̀sọ́ àwọn olùyanjú àti pé àwọn aṣàmúlò wa ti gba ìjẹ́risí láti mú kí agbègbè ìṣòwò tó ní àbò. Pẹ̀lú gbogbo àwọn ìgbésẹ̀ ìpamọ́ tí a ti gbé o lè fọkànbalẹ̀ torí o mọ̀ wípé àlàyé àti kírípítò rẹ wà ní àbò pẹ̀lú wa.
Èyí ni bí o ṣe lè bẹ̀rẹ̀ si ní ra Bitcoin lóri Paxful:
- Forúkọsílẹ̀ fún àkánti Paxful - Ṣẹ̀dá àti jẹ́risí àkántì rẹ láti gba wálẹ́ẹ̀tì Bitcoin ọ̀fẹ́ pẹ̀lú àbò 2FA. Ìṣètò àkántì rẹ ó rọrùn o sì le ríi ṣe láarín ìṣẹ́jú. Nkan tí o nílò ni àdírẹ́ẹ̀sì ímeèlì tó wúlò, nọ́mbà fóònù, àti ID láti bẹ̀rẹ̀.
-
Sàwáàrí olùtajà - Tẹ Rà láti àsàyàn àkọ́kọ́ kí o yan Rà Nísìín. Sètò oye tí o fẹ́ ná, kọ́rẹ́nsì tí o fẹ́, àti ìlànà ìsanwó rẹ tí o yàn láàyò ní wíjẹ́ẹ̀tì ẹ̀gbẹ́ láti wá àwọn olùtajà agbègbè àti ti òkè òkun tó báramu pẹ̀lú àwọn ìbéèrè rẹ.
A gbà ọ nímọ̀ràn láti ṣé gbogbo Irú Aṣàmúlò (Aṣojú, Alábáṣiṣẹ́pọ̀, abbl.) láti ṣàfihàn àwon olùtajà to ṣeé fọkàntán jùlọ tó ti lá àfikún àyẹ̀wò àbò kọjá láti ọ̀dọ̀ Paxful. - Ka àwọn ìbéèrè - Tẹ bótínì Rà láti wo àwọn àdéhùn olùtajà. Ó dá lórí ìlànà ìsanwó ló fi jẹ́ pé àwọn olùtajà ìmíìn ma ń bèrè pé kí o pèsè àwọn owó láti wálẹ́ẹ̀tì ayélujára re, f̣ọ́tò ìwe ìfowósílè bánkì, àbi ẹ̀dá rìsíìtì káàdì ẹ̀bùn tí o rà. Àwọn olùtajà ìmíìn ma ń bèrè pékí o ya àwòran tí o ti ń di ID lọ́wọ́ fún àfikùn bàbò.
- Bẹ̀rẹ̀ Òwò - Tí o bá lẹ̀ pa gbogbo àwọn àdéhùn olùtajà mọ́, ṣètò oye Bitcoin tí o fẹ́ rà nínu wíjẹ́ẹ̀tì kí o tẹ Rà nísìín láti bẹ̀rẹ̀ òwò náà. Èyí ma sí ìtakúrósó ẹ̀sẹ̀kẹsẹ̀ pẹ̀lú olùtajà tí o ti máa gba àwọn àfikún ìtọ́sọ́nà nípa bí o ṣe máa parí òwò náà. Ìtakúrósó ẹ̀sẹ̀kẹsẹ̀ ma ń ṣe ìgbàsílẹ̀ gbogbo ìfiránṣẹ́ á sì dáàbòbò ẹ tí o bá kọlù ìjàmbá kankan, torínáà má bá èyàn sọ̀rọ̀ níta Paxful.
- Fi ìsanwó ránṣẹ́ àti gba BTC rẹ - ní kété tí o bá ti pèsè gbogbo ìbéèrè, tí olùtajà bá ti fún ọ láṣẹ, fi ìsanwó ránṣẹ́ kí o tẹ Ti sanwó lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀. Ní báyìí, BTC olùtajà ti wà ní títìpa ní ẹ́síkírò láti dína kí olùbádòwòpọ̀ rẹ gba ìsanwó rẹ láì yànda kírípítò. Ní kété tí olùtajà bá ti jẹ́risí ìsanwó rẹ, a máa yànda Bitcoin láti àa wá firánṣẹ́ sì Wálẹ́ẹ̀tì Paxful rẹ.
Nkan tó kù lásán ni pé kí o fún olùtajà ní èsì ìrírí rẹ, lóbátán! Fún àlàyé síi, o lè wo fídíò ẹ̀kunrẹ́rẹ́ tó ṣàpèjúwe nípa bí o ṣe lè ra Bitcoin lóri Paxful.
Tí o bá ní ìbéèrè kankan, jọ̀ọ́ tẹ àmì ìtakúrósó tó wà nísàlẹ̀ lẹ́gbẹ́ ọ̀tún ojù-ìwé láti kàn sí ẹgbẹ́ àtìlẹ́yìn wa. A wà fún ẹ 24/7 - pẹ̀lú ojó ìsinmi gan!
Ríra Bitcoin rọrùn ó sì ní àbò, ṣùgbọ́n má wo ti ọ̀rọ̀ ẹnu wa nìkan-ka àwọn èsì láti àìmọye àṣàmúlò wa kárí àgbaye.