The Affiliate Program has been temporarily paused as we make changes to create a fair and sustainable program for the Paxful community. Learn more here.

Ìbánipolówó Paxful

Pa Owó fún Mímú àwọn Èèyàn wá Paxful

Ètò Ìbanipolówó Bitcoin wa n ṣe ìrànwọ́ fún ìwọ láti mú òmìnira ìnáwó bá àwùjọ rẹ. Gẹ́gẹ́ bíi àjẹṣẹ́kù, ìwọ náà yóò gba owópa wọlé déédé.

Mú àwọn èèyàn wá Paxful

Owó-àpawolé ẹṣẹ̀kẹsẹ̀ lórí Gbogbo Òwò kọ́ọ́kan

O yóò máa pa owó ní gbogbo ìgbà tí àwọn èèyàn tí ìwọ́ pè sí Paxful, àti àwọn tí àwọn náà pè, bá ra Bitcoin.

Owó Ìpawọlé lóri Gbogbo Òwò

O yóò máa pa owó ní gbogbo ìgbà tí àwọn èèyàn tí ìwọ́ pè sí Paxful, àti àwọn tí àwọn náà pè, bá ra Bitcoin.

Gba 50% Owósan Ẹ́síkírò Gba 50% Owósan Ẹ́síkírò

Nígbà tí àwọn èèyàn tí o pè bá ra Bitcoin lóri Paxful.

Gba 10% Owósan Ẹ́síkírò Gba 10% Owósan Ẹ́síkírò

Nígbà tí àwọn èèyàn tí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ pè bá ra Bitcoin lóri Paxful.

Kílódé tí ó fi yẹ kí ìwọ́ di Abánipolówó?

Ètò Ìbanipolówó Bitcoin wa jẹ́ ọ̀nà tó dára fún ìwọ láti tan ọ̀rọ̀ kírípítò ká ní àwùjọ rẹ.

Wálẹ́ẹ̀tì BTC
J'èrè Bitcoin J'èrè Bitcoin

O máa pa 50% owósan ẹ́síkírò ní gbogbo ìgbà tí ọ̀kan lára àwọn èèyàn tí ìwọ́ pè wá rajà bá ra Bitcoin.

Nẹ́tíwọọkì tó n dàgbàsókè
Ṣe Ìdàgbàsókè Nẹ́tíwọọkì Rẹ Ṣe Ìdàgbàsókè Nẹ́tíwọọkì Rẹ

Ìwọ yóò pa 10% owósan ẹ́síkírò ní gbogbo ìgbà tí èèyàn kan lára àtànká nẹ́tíwọọkì rẹ bá ra Bitcoin.

Gba owó jáde
Gba Owó Jáde ní Ìgbàkíígbà Gba Owó Jáde ní Ìgbàkíígbà

Lọ́gán tí ìwọ bá ti gba ó kéré jù Bitcoin tí ó tó 10 USD, ìwọ́ lè gba àwọn owópa rẹ jáde sínu wálẹ́ẹ́tì Paxful rẹ bí ìgbàkíígbà tí ìwọ bá fẹ́.

Di Abánipolówó

Báwo Ní Ó ṣé n Ṣiṣẹ́?

Ó rọrùn gan, ní òtítọ́ – di abánipolówó Bitcoin ní àwọn ìgbésẹ̀ mẹ́ta ní kíákíá.

Di Abánipolówó
Pe Ẹnikẹ́ni Pe Ẹnikẹ́ni

Pín kóódù Ìbánipolówó rẹ tàbí ìtọ́kasí lóri òpó ayélujára, àwọn àpéjọ kírípítò, tàbí àwọn àwùjọ. Ìwọ́ le rí kóódù àdáyàn tàbí ìtọ́kasí rẹ lábẹ Dásíbọọdù Abánipolówó rẹ (wẹ́ẹ́bù) tàbí táábù Abánipolówó (alágbèéká).

Di Abánipolówó
Pe Wọ́n sí Òwò Pe Wọ́n sí Òwò

Kọ́ àwọn tí ìwọ́ pè wá rajà ní ẹ̀kọ́ nípa kírípítò àti bí wọ́n ṣe le ṣ'òwò lóri Paxful. Gbogbo ìgbà tán bá ra Bitcoin, ìwọ yóò gba 50% owósan ẹ́síkírò wọn. Ìwọ yóò tún pa 10% owósan ẹ́síkírò ní gbogbo ìgbà tí ọ̀kan lára àwọn tán pe wá rajà bá ra Bitcoin lóri Paxful.

Di Abánipolówó
Gba Owó Gba Owó

Ṣe àmójútó ìṣe àwọn tí ìwọ́ pè wá rajà láti Dásíbọọdù Abánipolówó rẹ kí ìwọ́ wo àwọn owópa rẹ dàgbà sókè láìfọwọ́yí. Lọ́gán tí àwọn owópa rẹ bá ti tó ó kéré jù 10 USD, ìwọ́ lè gba owó jáde sí wálẹ́ẹ́tì Paxful rẹ.

Kí A Mú Ọ Bẹ̀rẹ̀
Ó dùn létí àbí? Ó dùn létí àbí? Jẹ́ Kí A Mú Ìwọ́ Bẹ̀rẹ̀!

Ṣẹ̀dá àkántì ọ̀fẹ́ rẹ lórí Paxful kí ìwọ́ sì bẹ̀rẹ̀ sí ní pe àwọn èèyàn.

Abánipolówó FAQ

Ó ṣeéṣe kí ìwọ́ ní àwọn ìbéèrè díẹ̀ lọ́kàn. Ní abẹ́, a ti dáhùn díẹ̀ lára àwọn èyí tó gbajúmọ̀ jù.

Kíni Paxful?
Paxful jẹ́ ibi ìtajà enìkan-sí-ẹnìkejì tí ó gbà ọ́ láàyè láti ra tàbí ta kírípítò nípasẹ̀ lílo èyíkéyìí àwọn àṣàyàn ìsanwó tán lé ní 300. Ó dàbí eBay, ṣùgbọ́n fún owó -- tí kò sì ní àwọn ìdiwọ̀n kankan. A ní ó lé ní míllíọ̀nù 4.8 àwọn aṣàmúlò láti gbogbo àgbáyé. Gbogbo òwò lóri Paxful ní ètò ẹ́síkírò wa n dáàbò bò, tó túnmọ̀ sí pé ìwọ́ lè ṣe Ìdúnadúrà tí o mọ̀ wípé àwon owó rẹ ní ààbò lórí.
Níbo ni mo ti lè wo àwọn owópa abánipolówó mi?
O lè wo àwọn owópa rẹ ní àwọn dásíbọọdù abánipolówó àti olùtajà rẹ.
Ṣé mo lè ṣẹ̀dá àkànṣe àwọn ìtọ́kasí abánipolówó fún àwọn ànfààní ìṣàmójútó?
Bẹ́ẹ̀ni. Lóri dásíbọọdù Abánipolówó rẹ, ìwọ́ le ṣ'èdá àwọn ìtọ́kasí tán ṣeé ṣọ́ lábẹ́ abala ÌDÁNIMỌ̀ ìṣàmójútó, láti pín pẹ̀lú àwọn apèwárajà kọ́rẹ́nsì kírípítò rẹ.
Kíni a kò f'àyè gbà?
Láti ríi dájú wípé gbogbo wá wà ní abala kan nípa oun tí a f'àyè gbà àti oun tí a kò fàyè gbà, a tí ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìṣe tí ìwọ gbọdọ̀ yẹra fún gẹ́gẹ́ bíi Abánipolówó sí abẹ́.

  • Ṣíṣẹ̀dá àkántì jù ẹyọ̀kan lọ - ẹyọ̀kan ní ìwọ́ lè ní lórí Paxful.
  • Lílo àwọn àtúnjúwe (fífiṣọwọ́) láti wẹ́búsaìtì rẹ lọ sí wẹ́búsaìtì Paxful.
  • Lílọ́wọ́ sí ìṣe jìbìtì láti j'èrè àwọn apèwárajà.
  • Ríra ìpolówó fún àwọn ìṣèbéèrè ọjà bíi: Paxful, paxful.com, tàbí àwọn ayédèrú mííràn - pẹ̀lú àwọn ẹ̀yà àṣìkọ.
  • Lílo àwọn ìṣèbéèrè ọjà àwọn ilé-iṣẹ́ olúdíje mííràn fún ìpolówó ọjà Paxful - àti fífi Paxful wé àwọn ọjà mííràn, fífi wọ́n hàn ní ọ̀nà tí kò dára.
  • Títẹ ìròyìn èké láti fa àwọn oníbàárà púpọ̀ síi, tàbí ṣíṣi oníbàárà lọ́nà ní èyíkèyí ọ̀nà.
  • Pípààrọ̀ owósan lóri àwọn owópa Abánipolówó rẹ lórí Paxful.
Ṣé ìwọ́ fẹ́ mọ̀ síi? Wo Ìfenukò Ìlò Ètò Ìbanipolówó wa.
Kíni Ètò Ìbanipolówó Paxful, àti wípé báwo ló ṣé n ṣiṣẹ́?
Ètò Ìbánipolówó Paxful jẹ́ ànfààní tó móríwú fún ọ láti jẹ ẹ̀bùn fún títan Paxful ká láàrin gbogbo èèyàn tán wà ní àrọ́wọ́tó rẹ. Ó rọrùn ní òtítọ́ – ìwọ́ mú àwọn èèyàn wá Paxful, kí o sì j'èrè ìpín owósan ẹ́síkírò wọn ní gbogbo ìgbà tán bá ra kírípítò lóri Paxfull. O máa pa 50% owósan ẹ́síkírò* fún àwọn èèyàn tí ìwọ mú wá Paxful, àti 10% owósan ẹ́síkírò* fún àwọn èèyàn tí wọ́n mú wá Paxful. Eléyìí kò sì kìí ṣe ẹ̀ẹ̀kan, ṣùgbọ́n gbogbo ìgbà tán bá ra kírípítò lóri Paxful. O lè kọ́ nẹ́tíwọọkì apèwárajà kọ́rẹ́nsì kírípítò rẹ ní ìrọ̀rùn nígbà tí ìwọ́ bá fi ìtọ́kasí ìbánipolówó rẹ sínu àròkọ tí ìwọ́ ṣẹ̀dá, pín-in lórí òpó ayélujára, tàbí polówó rẹ lóri wẹ́búsaìtì rẹ.
Kínni ìlànà owó-èrè fún ọ̀kọ̀ọ̀kan ìpele ètò náà?
O maa gba owó ní gbogbo ìgbà tí ọ̀kan lára àwọn àpèwárajà rẹ, tàbí àwọn àpèwárajà wọn bá parí òwò lóri Paxful ní àṣeyọrí. Iye tí ìwọ yóò gba ní a ṣí kó dá lóri dèèdé owó ẹ́síkírò, tí ó jẹ́ 1% iye tóo d'ókoòwò, àyàfi tí owó ẹ́síkírò bá kéré sí 1%. Tí owó ẹ́síkírò bá kéré sí 1%, a yóò ṣí owó ìbánipolówó dá lóri iyekíye tí owó ẹ́síkírò bá jẹ́ lọ́wọ́. Ètò ìsanwó ni ìwọ̀nyíí: Ìpele 1: O yóò gba 50% dèèdé owósan ẹ́síkírò nígbà tí aṣàmúlò bá ra kírípítò. Ìpele 2: Ìwọ yóò gba 10% dèèdé owósan ẹ́síkírò nígbà tí aṣàmúlò bá ra kírípítò.
Irú àròkọ àti àwọn orísun ìpolówó wo ní àwọn ọ̀nà tán dára jù láti pe èrò sí ìtọ́kasí abánipolówó mi?
Àwọn oríṣirííṣi orísun ní wọ́n wà tán le ṣiṣẹ́ fún ìwúlò rẹ, pẹ̀lú búlọ̀ọ̀gì rẹ, wẹ́búsaìtì rẹ, Google AdWords, Yandex Direct, Yahoo/Bing ads, àwọn nẹ́tíwọọkì ìpolówó alágbèéká, YouTube àti àwọn ìkànnì ìdárayá àti ìṣòwò mííràn. Òpó ayélujára ìgbàlódé náà jẹ́ irinṣẹ́ gidi láti ràn ìwọ lọ́wọ́ pẹ̀lú gbígba Bitcoin fún àwọn ìbánipolówó. Ó dára láti lo àwọn ÌDÁNIMỌ̀ ìṣàmójútó fún gbogbo oríṣirííṣi ìpolówó to bá ṣe, kí ìwọ́ lè ṣe àkíyèsí ǹkan tó n ṣiṣẹ́ jù fún ọ kí ìwọ́ sì kọ́ ẹ̀kọ́ láti ibẹ̀.
Báwo ní ẹ ṣé n ṣe ìmúdójúìwọ̀n àwọn ìṣirò sí lóri Dásíbọọdù Abánipolówó mi?
A máa n ṣe ìmúdójúìwọ̀n àwọn ìṣirò ní tòótọ́ lóri Dásíbọọdù Abánipolówó rẹ. Èyíówù to bá rí lóri dásíbọọdù náà yóò sọ bí ǹkan ṣe rí lọ́wọ́ yìí ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.
Kílódé tí díẹ̀ lára àwọn àpèwárajà mi ṣe n ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn òwò, tí àwọn t'ókù kàn forúkọsílẹ̀ láì ṣe òwò kankan?
Àwọn èèyàn ní àwọn ìnílò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn díẹ̀ le fẹ́ ra Bitcoin àkọ́kọ́ wọn lóri Paxful kí wọ́n sì dìímú fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù tàbí ọdún, tí àwọn t'ókù sì tèsíwájú láti lo ìkànnì náà fi rà tàbí tà síi. Ìpele iṣẹ́ àwọn àpèwárajà rẹ tún lè dá lóri irú àròkọ to bá ṣẹ̀dá láti pè wọ́n àti àwọn tí ìwọ n f'ojú sùn.
Ìgbà wo ní èmi yóò rí owó gbà?
Àwọn owópa rẹ nípasẹ̀ àwọn apèwárajà kọ́rẹ́nsì kírípítò rẹ máa n sábà wọlé sí wálẹ́ẹ́tì Abánipolówó kété tí àwọn to pè wá rajà báti parí òwò. Lọ́gán to bá ti kó owópa abánipolówó Bitcoin tó tó 10 USD jọ, ìwọ́ lè kó wọn lọ sí wálẹ́ẹ́tì Paxful rẹ ní ìgbàkíígbà to bá fẹ́. Lọ́gán to bá ti pa Bitcoin tó tó 300 USD, a yóò nílò rẹ láti parí ìjẹríísí ìdánimọ̀ àti àdírẹ́ẹ̀sì. Pro Tip: O lè ta owópa Bitcoin rẹ lóri ìkànnì wa fún àlékún èrè!
Níbo ni mo ti lè rí ìtọ́kasí abánipolówó mi?
O lè rí ìtọ́kasí abánipolówó rẹ ní àwọn dásíbọọdù abánipolówó àti olùtajà rẹ.
Níbo ni mo ti lè wo àkànṣe àwọn ÌDÁNIMỌ̀ ìṣàmójútó mi?
Ní ọjọ́ iwájú, ìwọ yóò le wo àwọn ÌDÁNIMỌ̀ ìṣàmójútó rẹ lóri dásíbọọdù rẹ. Fetí l'éko!
Àwọn orílẹ̀-èdè wo ni kí n f'ojú sùn tí mo bá n wá àwọn àpèwárajà?
Paxful jẹ́ ti gbogbo ayé ó sì ṣeé lo fẹ́ẹ́rẹ̀ ní ibikíbi tó ní ìwọlé sí ayélujára. Fún ìdí èyí, èyíkèyí ibi ìtajà to bá fẹ́ f'ojú sùn kù sí ìwọ lọ́wọ́ - abẹ́ẹlẹ́, agbègbè, orílẹ-èdè tàbí òmíìràn. Lọ́wọ́lọ́wọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn aṣàmúlò wa ni wọ́n wá láti U.S., tí Africa, Asia, àti Latin America sì jẹ́ àwọn ibi ìtajà wa tán yára dàgbà jù.
Ìpele mélòó ló wà níbi Ètò Ìbanipolówó Paxful, àti wípé báwo ló ṣé n ṣiṣẹ́?
A kò fi ìdópin rẹ sí owópa Bitcoin fún àwọn apèwárajà nìkan nípasẹ̀ àwọn apèwárajà tààrà rẹ. Dípò, àwọn ìpele méjì ló wà níbi Ètò Ìbanipolówó Paxful -- ọ̀kan tààrà, ọ̀kan tí kìí ṣe tààrà: Ìpele 1: Àwọn àpèwárajà tán forúkọsílẹ̀ tààrà nípasẹ̀ ìtọ́kasí rẹ nìyíí. Tier 2: Àwọn àpèwárajà tán forúkọsílẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ìtọ́kasí láti ọ̀dọ̀ ọ̀kan lára àwọn àpèwárajà tààrà rẹ.
Tí àpèwárajà mi bá n d'ókoòwò pẹ̀lú àpèwárajà mííràn, ṣẹ́ máa sì gba owó-èrè ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́?
Tí méjì lára àwọn àpèwárajà rẹ bá n d'ókoòwò pẹ̀lú ara wọn, ìwọ yóò gba 25% gbogbo owópa lórí òwò náà dípò 50% tó yẹ kóo gbà tẹ́lẹ̀.
Èèyàn kan tí mo dá Paxful fún, forúkọsílẹ̀ láì lo ìtọ́kasí mi. Ṣé mo ṣì lè gba owó-èrè?
Ó ṣe, rárá. Àwọn owópa Abánipolówó ṣeéṣe láti ọ̀dọ̀ àwọn aṣàmúlò tán forúkọsílẹ̀ nípasẹ̀ ìtọ́kasí abánipolówó rẹ nìkan.
Mo ní òpó ayélujára ìgbàlódé tí ó nííṣe pẹ̀lú Bitcoin, àwọn tán tẹ̀lé mí n'ífẹ sí ríra àti títa bitcoin. Ṣé kín ṣe àfihàn Paxful gẹ́gẹ́ bíi ọ̀nà láti ṣe bẹ́ẹ̀?
Lọ́fẹ̀ẹ́! Paxful jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tán rọrùn lágbayé fún ẹnikẹ́ni, ní ibikíbi láti ra tàbí ta Bitcoin. Àwọn àpèwárajà kọ́rẹ́nsì kírípítò rẹ lè forúkọsílẹ̀ nípasẹ̀ lílo ìtọ́kasí abánipolówó rẹ kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ríra àti títa Bitcoin láàrin ìṣẹ́jú péréte! Gbogbo ìgbà tán bá rà lóri Paxful, ìwọ yóò gba ìpawọlé ìbanipolówó.