Ìfẹnukò Ìlò Olùránnilétí olùtajà

Ìfenukò Ìlò Olùtajà yìí kàn wà láti jẹ́ ìtọ́kasí ránpẹ́ fún olùtajà ni, kò sì fi ibikíbi rọ́pò Ìfenukò ÌlòPaxful.

Jọ̀wọ́ fi sí ẹ̀mí wípé ìwọ́ gba àwọn àdéhùn wọ̀nyíí nígbà tí ìwọ bá yan Paxful láti ṣ'òwò.

 1. Gẹ́gẹ́ bíi olùtajà, ìwọ́ gba gbogbo eewu àti layabílítì fún èyíkèyí jìbìtì tó bá wáyé lásìkò títa àwọn ǹkan ìní onídíjítà rẹ.
 2. Paxful ní ẹ̀tọ́ láti má dá owó kankan tó bá sọnù nípasẹ̀ jìbìtì tàbí àwọn owó tán san fún owósan ẹ́síkírò wa padà.
 3. Ojúṣe olùtajà ni èyíkèyí àti gbogbo ìsanwó owó orí.
 4. Láti fi ẹjọ́ sùn láàrin òwò, jọ̀wọ́ pè fún àríyànjiyàn kí ìwọ́ sì dúró kí àwọn olupẹ̀tùsí dá síi.
 5. Kìí ṣe ojúṣe Paxful ní àwọn ọ̀ràn bíi wípé ìwọ́ tú ǹkan ìní onídíjítà sílẹ̀ kí ìsanwó tó parí.
 6. Paxful kò f'àyè gba àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyíí ó sì le já sí ìfòfindè àkántì rẹ:
  1. Àtúntà àwọn káàdì ẹ̀bùn
  2. Pínpín àwọn àlàyé tí kìíṣe ti ẹ́síkírò láàrin òwò
  3. Dídá òwò tí kìíṣe ti ẹsíkírò
  4. Àìfèsì - àwọn olùtajà gbọdọ̀ máa f'èsì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀
  5. Ède àbùkù
  6. Fífarawé olùpẹ̀tùsí
  7. Ṣíṣẹ̀dá àwọn àkántì ju ẹyọkan lọ (láì gba àṣẹ)
  8. Ìdúnadúrà
  9. Mímọ̀ọ́mọ̀ má ju kírípítò sílẹ̀
  10. Èyíkèyí ìgbésẹ̀ jìbìtì mííràn