Ìfitónílétí Onípamọ́ ti Paxful, Inc.

Paxful, Inc. (tí a tún máa ńpè ní "Paxful," "àwa," "wa," tàbí "tiwa") gbé àwọn ìgbésẹ láti dáábòbò ìpamọ́ rẹ. Nínú Ìfitónílétí Onípamọ́ yíí (“Ìfitónílétí ”), a ṣe àpèjúwe àwọn irú àlàyé àdáni tí a lè gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ ní àsopọ̀ pẹ̀lú lílo àwọn wẹ́búsáìtì wa pẹ̀lú, ṣùgbọ́n kìí ṣe òpin sí, https://paxful.com/, Wálẹ́ẹ̀tì Paxful, ìkànnì ìdókòwò bitcoin wa lórí ayélujára, áàpù ẹ̀rọ alágbèéká, àwọn ojú-ìwé ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ àwùjọ, tàbí àwọn ohun-ìní ayélujára mííràn (lápapọ, “wẹ́búsáìtì”), tàbí nígbàtí o bá lo èyíkèyí àwọn ọjà, àwọn iṣẹ́, àkóónú, àwọn ẹyà, àwọn ìmọ̀-ẹ̀rọ , tàbí àwọn iṣẹ́ tí à ńṣe (lápapọ̀, “Àwọn Iṣẹ́”).

A ṣètò ìfitónílétí yíí láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti gba àlàyé nípa àwọn ìṣe àṣírí wa àti láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ọ láti lóye àwọn yíyan àṣírí rẹ nígbàtí o bá lo wẹ́búsáìtì àti Àwọn Iṣẹ́ wa. Jọ̀wọ́ ṣe àkíyèsi pé àwọn Iṣẹ́ ìnájà wa lè yàtọ nípasẹ̀ agbègbè.

Fún gbogbo àwọn ìdí, ẹ̀yà èdè Gẹ̀ẹ́sì ti ìfitónílétí Onípamọ́ yíí yóò jẹ ògidì, ohun-èlò ìṣàkóso. Ní ìṣẹlẹ ti èyíkèyí èdè-àìyedè láàrín ẹ̀yà èdè Gẹ̀ẹ́sì lórí ìfitónílétí Onípamọ́ yíí àti èyíkèyí ìtumọ àtẹlè sí èyíkèyí èdè mííràn, ẹ̀yà èdè Gẹ̀ẹ́sì yóò ṣàkóso àti darí.

Àlàyé ti ara ẹni tí a gbà

A gba àlàyé tí ó ní ìbátan sí ọ (“Dátà Àdáni”) ní àsopọ̀ pẹ̀lú lílo wẹ́búsáìtì, Àwọn iṣẹ wa. tàbí bíbẹ́ẹ̀kọ́ nínú ipò ìbátan wa pẹ̀lú rẹ. Àwọn oríṣi Dátà Àdáni tí a lè gbà láti ọ̀dọ̀ rẹ lè pẹ̀lú:

Àwọn dátà ìtàn-ayé-ènìyàn, pẹ̀lú:

 • Orúkọ
 • Àdírẹ́ẹ̀sì ímeèlì
 • Nọ́mbà fóònù
 • Orílẹ̀-èdè
 • Àdírẹ́ẹ̀sì ní kíkún
 • Ọjọ́ Ìbí

Àwọn àlàyé Àkántì Paxful, pẹ̀lú:

 • Orúkọ aṣàmúlò
 • Àlàyé aṣàpèjúwe Aṣàmúlò ni apákan “Nípa mi”
 • Fọ́tò Asàpèjúwe
 • Déètì ìdarapọ̀mọ́
 • Kọ́rẹ́ńsì Àiyípadà
 • Agbègbè Àkókò
 • Èdè Àiyípadà

Akitiyan Àkántì Paxful, pẹ̀lú:

 • Àwọn ìfiránṣẹ́ ìtàkúrọ̀sọ òwò (èyítí ó lè ní àlàyé owó tí o bá pèsè ẹ̀ fún àwọn olùtajà)
 • Àwọn Àsomọ́ ìtàkúrọ̀sọ òwò
 • Akitiyan òwò
 • Ìtàn ìdúnàádúrà
 • Orúkọ Abánipolówó
 • Ìdánimọ̀ Abánipolówó
 • Ìtọ́kasí Abánipolówó
 • Àwọn ìdúnàádúrà Abánipolówó
 • Àwọn ìnájà ti a ṣẹ̀dá
 • Àdéhùn Ìfilọ̀ ìnájà
 • Àwọn ìtọ́nísọ́nà òwò
 • Àwọn ìfitónilétí Àkántì
 • Ipò Àkántì

Dátà tí ó jọmọ́ Wálẹ́ẹ̀tì dúkìá onídíjítà rẹ, pẹlú:

 • Kọ́kọ́rọ́ Àdáni
 • Kọ́kọ́rọ́ Gbogbogboo
 • Aṣẹ́kú owó Wálẹ́ẹ̀tì
 • Ti gba ìdúnàádúrà
 • Ti fi ìdúnàádúrà ránṣẹ́

Ti gba dátà ní àsopọ̀ pẹ̀lú “Mọ oníbárà rẹ” (KYC) Ìbámu, pẹ̀lú:

 • Ìdánimọ̀ tí ìjọba ṣejáde
 • Ìfijẹ́rìí sí àdírẹ́ẹ̀sì
 • Àwọn fọ́tò, tí o bá yàn láti pèsè wọn fún wa
 • Fídíò, tí o bá yàn láti pèsè wọn fún wa

Èrọ àti Dátà Lílò Wẹ́búsáìtì, pẹ̀lú:

 • Àdírẹ́ẹ̀sì IP
 • Kúkì Ìdánimọ̀ àti /tàbí àwọn ìdánimọ̀ ẹ̀rọ mííràn
 • Àlàyé tí ó jọmọ́ ìráyè sí Wẹ́búsáìtì rẹ, gẹ́gẹ́bí àwọn àbùdá ẹrọ, ọjọ & àkókò
 • Àwọn àyànfẹ èdè
 • Àlàyé lórí àwọn ìṣe lákókò lílo Wẹ́búsáìtì náà

Bí a ṣe lo dátà rẹ

Àwọn ìdí ìṣòwò èyítí a gbà, ìlò, ìdádúró, àti pínpín Dátà Àdáni rẹ lè pẹ̀lú:

 • Láti pèsè Àwọn iṣẹ́ nípasẹ̀ lílo Wẹ́búsáìtì, pẹ̀lú sí:
  • Forúkọsílẹ̀, ṣẹ̀dá, ati ṣètọ́jú àkántì rẹ;
  • Ṣe ìfàṣẹsí ìdánimọ̀ rẹ àti / tàbí ìráyè sí àkántì kan, tàbí ṣe ìrànlọ́wọ́ fún àwọn olùtajà láti jẹ́rìsí ìdánimọ̀ rẹ;
  • Pilẹ̀, dẹ̀rọ̀, ṣètò, àti / tàbí ṣiṣẹ àwọn ìdúnàádúrà;
  • Sọ̀rọ̀ pẹ̀lú rẹ nípa àkántì rẹ tàbí èyíkèyí Àwọn iṣẹ́ tí o lò;
  • Ṣe iṣẹ́ ìrówó-yíyá-gbà, KYC, tàbí àwọn àtúnyẹ̀wò irúfẹ́ mííràn;
  • Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn ìbẹ̀wẹ̀; tàbí
  • Ṣe àfiwé àlàyé fún ìṣe déédé àtí àwọn ìdí ìjẹ́rìísí.
 • Láti ṣàkóso ewu àti ààbò fún ọ, àwọn ènìyàn mííràn, àti Wẹ́búsáìtì àti Àwọn Iṣẹ́.
 • Láti pèsè ìrírí ti ara ẹni àti ṣe àwọn ohun tí o fẹ́.
 • Láti ní òye àwọn oníbárà dáradára àti bí wọn ṣe lò àti ṣepọ̀ pẹ̀lú Wẹ́búsáìtì àti Àwọn Iṣẹ́.
 • Láti tà fún ọ
 • Láti pèsè Àwọn iṣẹ́ ti ara ẹni, àwọn ìnájà, àti àwọn ìgbéga lórí Wẹ́búsáìtì wa àti àwọn Wẹ́búsáìtì ẹnìkẹta.
 • Láti pèsè fún ọ àwọn àṣàyàn agbègbè pàtó , àwọn iṣẹ́ ṣíṣe, àti àwọn ìnájà.
 • Láti tẹ̀le àwọn ìlànà àti àwọn àdéhùn wa, pẹ̀lú, ṣùgbọ́n kìí ṣe òpin sí, àwọn ìfihàn àti àwọn ìdáhùn ní ìdáhùn sí èyíkèyí ìbéèrè láti ọ̀dọ̀ àwọn aláṣẹ agbófinró àti / tàbí àwọn olùtọ́sọ́nà ní ìbámu pẹlú èyíkèyí òfin tó wà fun ún, òfin, ìlànà, ìdájọ́ tàbí àṣẹ ìjọba, aláṣẹ ìtọ́sọ́nà ti ìdájọ́ tó pegedé, ìbéèrè àwárí tàbí ìlànà òfin tó jọra.
 • Láti yanjú àwọn àríyànjiyàn, gba owósan, tàbí ìtúsíta-okùnfà àwọn ìṣòro
 • Láti pèsè iṣẹ oníbárà fún ọ tàbí bíbẹ́ẹ̀kọ́ bá ọ sọ̀rọ̀.
 • Láti ṣàkóso ìṣòwò wa.

A tún lè ṣe ìlànà Dátà Àdáni fún àwọn ìdí mííràn tí ó dá lórí ìfohùnsí rẹ nígbàtí òfin tó bàa mu bá bèèrè fún un.

Àwọn orísun tí a ti ń gba dátà àdáni

À ń gba dátà àdáni láti àwọn orísun tí ó níye, pẹ̀lú

 • Tààrà láti ọ̀dọ̀ rẹ: À ń gba Dátà Àdáni tààrà láti ọ̀dọ̀ rẹ nígbàtí o bá lo Wẹ́búsáìtì tàbí Àwọn Iṣẹ wa, ní ìbásọ̀rọ̀ pẹ̀lú wa, tàbí ìbáṣepọ̀ tààrà pẹ̀lú wa.
 • Láti ọdọ àwọn olùpèsè iṣẹ́ àti / tàbí àwọn olùṣaáyan dátà tí ó ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa ní pípèsè Wẹ́búsáìtì tàbí Àwọn Iṣẹ́ náà: A lè gba àwọn olùpèsè iṣẹ́ láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa ní ìṣètò Wẹ́búsáìtì tàbí Àwọn iṣẹ́ fún ọ, ní ìtọ́sọ́nà wa àti fún wa. Àwọn olùpèsè iṣẹ́ wọ̀nyí lè gba àlàyé nípa rẹ kí wọ́n pèsè rẹ fún wa.
 • Láti ọ̀dọ̀ àwọn aṣàmúlò Wẹ́búsáìtì Paxful òmíràn tàbí láti ọ̀dọ̀ àwọn abánipolówó tí o sopọ̀ pẹlu Wẹ́búsáìtì Paxful tàbí Àwọn Iṣẹ́: Àwọn aṣàmúlò òmíràn lè fún wa ní àlàyé nípa rẹ ní àsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ìdúnàádúrà tàbí àwọn ìtàkurọ̀sọ. Àwọn abánipolówó lè tún pèsè àlàyé fún wa nípa rẹ tí ó ní ìbátan sí àwọn ìbáraẹniṣepọ̀ rẹ tàbí àwọn ìdúnàádúrà pẹ̀lú irú àwọn abánipolówó bẹ́ẹ̀.
 • Láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹnì-kẹta tí ó lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa láti jẹ́rìsí ìdánimọ̀, ṣe ìdíwọ́ jìbìtì, àti dáàbò bo ààbò àwọn ìdúnàádúrà.
 • Láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹnì-kẹta tí ó lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa láti ṣàgbéyẹ̀wò ìrówó-yíyá-gbà rẹ, tàbí ipò ìṣúná.
 • Láti ọ̀dọ̀ àwọn ẹnì-kẹta tí ó lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún wa láti ṣe ìtúpalẹ Dátà Àdáni, ṣàtúnṣe Wẹ́búsáìtì tàbí Àwọn Iṣẹ́ wa tàbí ìrírí rẹ lórí rẹ, ta àwọn ọjà tàbí àwọn iṣẹ́, tàbí pèsè àwọn ìgbéga àti àwọn ìnájà fún ọ.
 • Láti àwọn ìkànnì ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ àwùjọ, tí o bá ṣepọ̀ pẹ̀lú wa nípasẹ̀ ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ àwùjọ.

Bí a ṣe ń pín dátà

Lábẹ àwọn àyídáyidà kan, a lè ṣàfihàn Dátà Àdáni kan pẹ̀lú àwọn ènìyàn mííràn. Àwọn ìsọ̀rí ti àwọn ènìyàn tí a lè pín Dátà Àdáni pẹ̀lú:

 • Àwọn olùpèsè iṣẹ́ àti / tàbí àwọn olùṣaáyan dátà: A lè pín Dátà Àdáni pẹ̀lú àwọn olùpèsè iṣẹ́ ẹnìkẹta tí o ṣe àwọn iṣẹ àti àwọn iṣẹ́ ni ìtọ́sọ́nà wa àti ní ipò wa. Àwọn olùpèsè iṣẹ́ ẹnì-kẹta wọ̀nyí lè, fún àpẹẹrẹ, fún ọ ní Àwọn iṣẹ́, jẹ́rìsí ìdánimọ̀ rẹ, ṣe ìrànlọ́wọ́ nínú àwọn ìdúnàádúrà ṣíṣe, fi àwọn ìpolówó àwọn ọjà àti iṣẹ́ wa ránṣẹ sí ọ, tàbí pèsè àtìlẹyìn oníbárà.
 • Àwọn ẹgbẹ́ mííràn sí àwọn ìdúnàádúrà, gẹ́gẹ́bí àwọn olùtajà: A lè pín àlàyé pẹlu àwọn olùkópa mííràn sí àwọn ìdúnàádúrà rẹ, pẹ̀lú àwọn aṣàmúlò mííràn láti ọ̀dọ̀ ẹnití ò ń ra dúkìá onídíjítà náà.
 • Àwọn ilé-ìṣúná àti àwọn ilé-iṣẹ́ mííràn tí ó kópa nínú rírán ọ lọ́wọ́ láti sanwó ní àsopọ̀ pẹ̀lú àwọn ìdúnàádúrà
 • Àwọn abánipolówó tí ó gba àwọn ìpeniwárajà láti Wẹ́búsáìtì wa
 • Àwọn ẹnì-kẹta mííràn fún àwọn ìdí ìṣòwò wa tàbí bí a ṣe gbà láàyè tàbí nílò nípasẹ̀ òfin, pẹ̀lú:
  • Láti tẹ̀lé èyíkèyí òfin, ìlànà tàbí ọranyàn àdéhùn, tàbí pẹ̀lú èyíkèyí òfin tàbí ìlànà ètò (gẹ́gẹ́bí àṣẹ ilé-ẹjọ tí ó tọ̀nà tàbí ìfìwépè ilé-ẹjọ́);
  • Láti fi ìdí múlẹ̀, ṣe, tàbí gbèjà àwọn ẹ̀tọ́ òfin;
  • Ní ìdáhùn si ìbéèrè ti ìbẹ̀wẹ̀ ìjọba kan, gẹ́gẹ́bí àwọn agbófinró tabi àṣẹ ìdájọ́;
  • Láti kàn-án-nípá Ìfẹnukò Ìlò ti Wẹ́búsáìtì wa tàbí àwọn ètò ìmúlò abẹ́nú wa;
  • Láti yàgò fún ìpalára àfojúrí tàbí pípàdánù owó, ní àsopọ pẹ̀lú ìṣèwádìí ti ìfura tàbí iṣẹ arúfin gangan, tàbí bíbẹ́ẹ̀kọ́ dáàbòbò àwọn ẹtọ́ wa tàbí ti àwọn mííràn, àwọn ohun-ìní, tàbí ààbò wa;
  • Láti dẹ̀rọ̀ rírà tàbí títà gbogbo tàbí apákan ti ìṣòwò Paxful. Fún àpẹẹrẹ, nípa pínpín dátà pẹ̀lú ilé-iṣẹ́ kan tí a gbèrò láti dàpọ̀ pẹ̀lú tàbí gbà nípasẹ̀ ̀; tàbí
  • Láti ṣe àtìlẹyìn àyẹwò ìwé-ajé wa, ìbámu, àti àwọn iṣẹ́ ìṣàkóso tó gbámúṣé.

Àwọn gbígbé dátà káríayé

Jọ̀wọ́ ṣe àkíyèsí pé a lè gbé Dátà Àdáni tí a gbà nípa rẹ lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè mííràn yàtọ̀ sí orílẹ-èdè èyítí a ti gba àlàyé náà. Àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyẹn lè má nì àwọn òfin ààbò dátà kanná bí orílẹ̀-èdè èyítí o ti pèsè àlàyé ní ìbẹrẹ. Nígbàtí a bá gbé Dátà Àdáni rẹ lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè mííràn, a gbé àwọn ìgbésẹ tí a ṣe ìpìlẹ̀ láti ríi dájú pé gbígbé rẹ wà ní ìbámu pẹ̀lú òfin tí ó rọ̀ mọ́ọ.

Kúkì àti ìpolówó orí ayélujára

 • Kúkì jẹ fáìlì ọ̀rọ̀ kékeré tí wẹ́búsáìtì ń fipamọ́ lórí kọ̀mpútà rẹ tàbí ẹ̀rọ alágbèéká nígbàtí o bá ṣàbẹwò sí wẹ́búsáìtì náà.
 • Wẹ́búsáìtì wa ńlo àwọn kúkì àti àwọn ìmọ̀-ẹrọ ìtọpinpin láti ṣiṣẹ́, àti láti dojúkọ ìpolówó tí o lè nífẹ sí. Fún àlàyé síwájú síi, jọ̀wọ́ tọka sí Ìlànà Kúkì wa.
 • Paxful lè jẹ́ alábáṣepọ̀ pẹ̀lú àwọn nẹ́tíwọọ̀kì ìpolówó ẹnìkẹta bóyá láti ṣe ìfihàn ìpólówó lórí Wẹ́búsáìtì Paxful tàbí lórí àwọn wẹ́búsáìtì ẹnìkẹta. Àwọn wẹ́búsáìtì wọnyí àti àwọn nẹ́tíwọọ̀kì ìpolówó ẹnì-kẹta kò ní ìṣàkóso nípasẹ̀ Paxful. Àwọn alábáṣiṣẹ́pọ̀ nẹ́tíwọọ̀kì Ìpolówó ńlo àwọn ìmọ-ẹrọ dátà láti gba àlàyé nípa àwọn iṣẹ orí ayélujára rẹ láti fún ọ ní ìpolówó tí o fojúsí tí ó dà lórí àwọn ìfẹ́ rẹ. Tí o bá fẹ láti máà ní àlàyé yíí fún ìdí tí ṣíṣe àwọn ìpolówó tí o fojúsí, o lè ní ànfàní láti jáde nípasẹ̀ lílọ sí:

Jọ̀wọ́ ṣe àkíyèsí èyí kò gbé ọ jáde kúrò ní ìpolówó iṣẹ́; ìwọ yóò tẹ̀síwájú láti máa gba àwọn ìpolówó aláìníìdámọ̀ tí kò dá lórí àwọn ìnífẹ́sí rẹ pàtó. O lè darí lílo àwọn kúkì ní ìpele aṣàwákiri kọọkan. Tí o bá kọ̀ àwọn kúkì, o tún lè lo Wẹ́búsáìtì wa, ṣùgbọ́n agbára rẹ láti lo díẹ nínú àwọn ẹyà tàbí àwọn agbègbè ti Wẹ́búsáìtì wa lè ní òpin.

Ìpamọ́ dátà

A ṣe ìfipamọ́ Dátà Àdáni fún àkókò tí ó ṣe pàtàkì fún àwọn ìdí èyítí a ṣe gbàá, tàbí fún àwọn àkókò bí àgbékalẹ̀ òfin tí ó rọ̀ mọ́ọ. Èyí lè fa ìfipamọ́ Dátà Àdáni fún àwọn àkókò tí ó tẹ̀lé ìdúnàádúrà kan. A ṣe àwọn ìgbìyànjú láti pa Dátà Àdáni rẹ́ ní kété tí a kò bá nílò rẹ̀ fún èyíkèyí àwọn ìdí ìṣòwò tí a ṣàlàyé lókè.

Ààbò dátà

Paxful tí ṣe àwọn ààbò tí a ṣe ìpìlẹ̀ láti dáàbòbò Dátà Àdáni rẹ, pèlú àwọn ìgbésẹ̀ tí a ṣe ìpìlẹ̀ láti yàgò fún pípàdánù Dátà Àdáni, ìlòkulò, àti ìráyè láìgbà àṣẹ àti ìṣàfihàn. Síbẹ̀, Paxful kò lè ríi dájú tàbí ṣe àtìleyìn ààbò tàbí àṣírí ti àlàyé tí o firánṣẹ sí wa tàbí gbà láti ọ̀dọ̀ wa nípasẹ̀ Íńtánẹẹtì tàbí àsopọ aláìlowáyà. Gbígbé dátà nípasẹ̀ Íńtánẹẹtì nígbàgbogbo ní ewu díẹ, bóṣelewù kí Paxful gbìyànjú tó láti dáàbòbò dátà ní kété tí ó bá ti gbàá ọ̀rọ̀ bùṣe.

Àwọn ọmọdé lábẹ́ ọdún 18

Wẹ́búsáìtì Paxful kò wà fún àwọn ọmọdé lábẹ́ ́ ọdún 18. A kìí mọ̀ọ́mọ̀ gba dátà láti ọ̀dọ̀ àwọn ọmọdé lábẹ́ ́ ọdún 18 láìsí ìfọwọ́sí òbí tí a jẹ́rìsí. Tí a bá mọ̀ pé a ti gba àlàyé, pẹlú Dátà Àdáni, láti ọ̀dọ̀ ẹni kọọkan lábẹ́ ́ ọdún 18 láìsí ìfọwọ́sí ti òbí, a yóò pa àlàyé yẹn rẹ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.

Àwọn ìyípadà sí ìfitónílétí Onípamọ́

Paxful ní ẹ̀tọ́ láti ṣe ìyípadà ìfitónílétí yíí láti ìgbà dé ìgbà. A yóò sọ fún ọ tí àwọn ìyípadà sí ìfitónílétí yíí nípa fífiránṣẹ ẹ̀yà tí a túnṣe ti ìfitónílétí yíí níbí, nípasẹ̀ ímeèlì, tàbí nípasẹ̀ ìfitónílétí ògúná lórí Wẹ́búsáìtì Paxful. A ṣe ìṣèdúró pé kí o ṣàyẹwò Wẹ́búsáìtì náà lórèkórè fún èyíkèyí àwọn àyípadà.

Kàn sí wa

Tí o bá ní ìbéèrè èyíkèyí nípa ìfitónílétí yíí, tàbí fẹ láti ṣe ìbéèrè pẹ̀lú wa nípa Dátà Àdáni tàbí àṣírí, jọ̀wọ́ kàn sí wa ní: [email protected]

Àfikún-àtẹ̀jáde EEA

Àwọn ìfitónílétí wọ̀nyí wà fún, àti pé a ṣeé ní ìyàsọ́tọ̀ fún, àwọn ẹnì-kọọkan tí ó ńgbé láàrín Agbègbè Ọrọ̀-ajé Yúróòpù (EEA).

Olùṣàkóso dátà

Olùṣàkóso fún Dátà Àdáni rẹ ní Paxful, Inc.

Àwọn ìpìlẹ̀ òfin fún Ìṣaáyan Dátà Àdáni

 • Sí iye tí a lo Dátà Àdáni láti ṣe àwọn ọranyàn àdéhùn tàbí àwọn ìbéèrè tí ìwọ ṣe ní àsopọ̀ pẹ̀lú àdéhùn kan, Abala 6 (1) (b) ti Ìlànà Ìdáàbòbò Dátà Gbogbogboò (“GDPR”) jẹ ìpìlẹ̀ òfin fún ìṣaáyan dátà wa.
 • Sí iye tí a lo Dátà Àdáni láti tẹ̀lé òfin ọranyàn lábẹ́ ́ EU tàbí òfin Ìpínlẹ̀ Ẹlẹgbẹ́, Abala 6 (1) (c) ti GDPR jẹ ìpìlẹ̀ òfin fún ìṣaáyan dátà wa.
 • Sí iye tí a lo Dátà Àdáni láti dáàbòbò àwọn ìnífẹ́sí pàtàkí ti àwọn ẹnì-kọọkan, Abala 6 (1) (d) ti GDPR jẹ ìpìlẹ̀ òfin fún ìṣaáyan dátà wa.
 • Sí iye tí a lo Dátà Àdáni ní ìlépa àwọn ìnífẹ́sí ìṣòwò ìbáòfinmu wa, Abala 6 (1) (f) ti GDPR jẹ ìpìlẹ̀ òfin fún ìṣaáyan dátà wa. Àtòkọ ti àwọn ìfẹ ìṣòwò ti ibaofinmu wa ní abala tí ó wà lókè ti ó ní àkọlé “Bí A Ṣe Lo Dátà Rẹ”.

Àwọn ẹ̀tọ́ Ìdáàbòbò dátà ti Ilẹ̀ Yúróòpù

Òfin Yúróòpù fún ìwọ ní àwọn ẹ̀tọ́ kan pẹ̀lú ọ̀wọ̀ sí Dátà Àdáni, pẹlú:

 • Ẹ̀tọ́ láti bèèrè wíwọlé sí àti àtúnṣe ti Dátà Àdáni rẹ.
 • Ẹ̀tọ́ láti bèèrè pé kí Paxful pa Dátà Àdáni rẹ kan rẹ́.
 • Ẹ̀tọ́ sí gbígbé dátà, èyítí ó pẹ̀lú ẹ̀tọ́ láti bèèrè ní pàtó Dátà Àdáni tí o ti pèsè fún wa ní gbígbé láti ọ̀dọ̀ wa sí ọ̀dọ̀ olùṣàkóso dátà mííràn.
 • Ẹ̀tọ́ láti yọkúrò èyíkèyí ìfọwọ́sí tí o ti pèsè fún Paxful láti gbà, lò, tàbí pín dátà rẹ nígbàkugbà. Jọ̀wọ́ ṣe àkíyèsí pé ìfọwọ́sí yíyọkúrò kò ní ipa sí ìbáòfinmu ti Paxful fún ìṣaáyan Dátà Àdáni rẹ ṣáájú yíyọkúrò rẹ.
 • Ẹ̀tọ́ láti tako bí Paxful ṣe ńṣaáyan Dátà Àdáni rẹ, dá lórí àwọn ààyè ní pàtó sí ipò rẹ kan.
 • Ẹ̀tọ́ láti bèèrè pé kí Paxful ní ìhámọ́ ńṣaáyan Dátà Àdáni rẹ, tí àwọn ipò òfin kan fún ìhámọ́ bá ṣe déédé.
 • Ẹ̀tọ́ láti sọ ẹ̀dùn ọkàn fún alábójútó àṣẹ ti Yúróòpù.

Jọ̀wọ́ ṣe àkíyèsí pé òfin tí ó rọ̀ mọ́ọ lè pèsè àwọn ìmúkúrò sí èyíkèyí àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyi, gba Paxful láàyè láti kọ̀ ìbéèrè rẹ, tàbí gba Paxful láàyè láti fa àkókò ìṣiṣẹ́ lórí ìbéèrè rẹ gùn. Paxful tún lè kàn sí ìwọ láti jẹ́rìsí ìdánimọ̀ rẹ, gẹ́gẹ́bí òfin ṣe gbàá láàyè, ṣáájú ìṣiṣẹ́ lórí ìbéèrè rẹ. Láti lo èyíkèyí àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyi, jọ̀wọ́ kàn si wa bí a ti ṣètò síwájú nínú abala tí ó wà lókè ti ó ní àkọlé “Kàn sí Wa”.

Àwọn gbígbé káríayé

A lè gbé Dátà Àdáni tí ó jọmọ́ ti àwọn olùgbé EEA sí àwọn orílẹ̀-èdè tí Ìgbìmọ Yúróòpù kò yì tíì rí láti pèsè ààbò tó péye fún, pẹ̀lú Amẹ́ríkà. Fún èyíkèyí irú àwọn gbígbé, Paxful ṣe àwọn ààbò tí a ṣe ìpìlẹ̀ láti ríi dájú pé Dátà Àdáni gba ìpéle ààbò tó pé. Tí o bá wà ní EEA, Paxful yóò gbé Dátà Àdáni rẹ nìkan: ti orílẹ̀-èdè tí yóò gbé Dátà Àdáni sí bá ti ní àṣẹ ìgbékọjá-ìloro ti Ìgbìmọ Yúróòpù; olùgbà ti Dátà Àdáni wà ní Orílẹ Amẹ́ríkà ó sì ti ní ìfọwọsí ti Ètò-ààbò onípamọ́ tó gbó pọn bí ẹ̀wù ìrìn ti Amẹ́ríkà-EU; Paxful ti fi àwọn ààbò tí ó yẹ sí ipò fún olúkúlùkù gbígbé, fún àpẹẹrẹ nípa wíwọlé sínú Àwọn òfin àdéhùn tó gbé wọn ti EU pẹlú olùgbà, tàbí; ìyàsọtọ òfìn àyàfi kan tí ó rọ̀ mọ́ èèwọ gbígbé gbogbogbò GDPR. Láti gba ẹ̀dà ti àwọn ìlànà ti Paxful ti ṣe láti ṣe àtìlẹyìn àwọn gbígbé ti dátà àdáni rẹ ní ìta EEA, kàn sí wa bí a ti ṣètò síwájú nínú abala ti o wa loke “Kàn sí Wa”.

Àfikún-àtẹ̀jáde California

Àwọn ìfihàn wọ̀nyí wà fún, àti pé a yà wọn sọ́tọ̀ fún, àwọn olùgbé ti Ìpínlẹ̀ California.

Àwọn ẹ̀tọ́ ìpamọ́ California rẹ

Sí iye tí a ṣàfíhàn àwọn àlàyé ti àdáni tí o ṣeé dámọ̀ kan nípa rẹ sí àwọn ẹgbẹ kẹta tí ó lòó fún àwọn ìdí títajà tààrà wọn, o ní ẹ̀tọ́ láti bèèrè àlàyé síwájú sí nípa àwọn olùgbà àlàyé rẹ. Láti lo ẹ̀tọ́ yíí, jọ̀wọ́ kàn sí wa bí a ti ṣàlàyé nínú abala tí ó wà lókè ti àkọlé “Kàn sí Wa.”

Máṣe Tọpinpin Ìfihàn

A kò ṣètò Wẹ́búsáìtì wa láti dáhùn sí “Máṣe Tọpinpin” àwọn ìfihàn agbára tàbí àwọn ìbéèrè.

Àwọn òtítọ́ Kíni Paxful nílò àlàyé ara ẹni rẹ fún?
Kí nìdí?

Àwọn ilé-iṣẹ ìṣúná yan bí wọn ṣe pín àlàyé ti ara ẹni rẹ. Òfin ìjọba àpapọ̀ fún àwọn oníbárà ni ẹtọ láti ṣe ìdópin díẹ ṣùgbọn kìí ṣe gbogbo pínpín. Òfin ìjọba àpapọ̀ tún nílò wa láti sọ fún ọ bí a ṣe ńgbà, pínpín, àti ààbò àlàyé ti ara ẹni rẹ. Jọwọ ka àkíyèsi yíí dáradára láti ní òyé ohun tí à ń ṣe.

Kíni?

Àwọn oríṣi àlàyé ti ara ẹni tí a gbà àti pín dàlé lórí ọjà tàbí iṣẹ tí o ní pẹlú wa. Àlàyé yíí lè pẹ̀lú:

 • Nọ́mbà ààbò olúkúlùkù tàbí àwọn aṣẹ́kú owó àkántì
 • Ìtàn ìsanwó tàbí ìtàn ìdúnàádúrà
 • Ìtàn kírẹdítì tàbí àwọn iye kírẹdítì

Tí o kò bá ṣe oníbárà wa mọ, a yóò tẹsíwájú láti pín àlayé rẹ bí a ti ṣàlàyé nínú àkíyèsí yíí.

Bí báwo?

Gbogbo àwọn ilé-iṣẹ ìṣúná nílò láti pín àlàyé ti ara ẹni ti àwọn oníbárà láti ṣiṣẹ ìṣòwò ojoójúmọ wọn. Nínú abala tí ó wà ní ìsàlẹ, a ṣe àtòkọ àwọn ìdí tí àwọn ilé-iṣẹ ìṣúná owó lè pín àlàyé ti ara ẹni ti àwọn oníbárà wọn; àwọn ìdí ti Paxful yàn láti pín; àti bóyá o lè ṣe ìdópin pínpín yíí.


Àwọn ìdí ti a fi lè pín àlàyé ti ara ẹni rẹ

Ṣe Paxful ńpín?

Ṣé o lè ṣe ìdópin pínpín yìí?

Fún àwọn ìdí iṣowo ojoojúmọ wa - gẹgẹbí láti ṣaáyan àwọn ìdúnàádúràrẹ, ṣètọjú àkántì (àwọn) rẹ, dáhùn sí àwọn àṣẹ kóòtù àti àwọn ìṣèwádìí òfin, tàbí ṣe ìjábọ̀ fún àwọn ilé-iṣẹ kírẹdítì

Bẹ́ẹ̀ni

Rárá

Fún àwọn ìdí ọjà títà wa - láti pèsè àwọn ọjá àti iṣẹ wa fún ọ

Bẹ́ẹ̀ni

Rárá

Fún títà àpapọ pẹlú àwọn ilé-iṣẹ ìṣúná mííràn

Bẹ́ẹ̀ni

Rárá

Fún àwọn abánipolówó wa ’àwọn ìdi ìṣòwò lójoojúmọ - àlàyé nípa àwọn ìdúnàádúrà rẹ àti àwọn ìrírí

Bẹ́ẹ̀ni

Rárá

Fún àwọn abánipolówó wa ’àwọn ìdi ìṣòwò lójoojúmọ - àlàyé nípa títọ-kírẹ́dítì rẹ

Rárá

A kìí pín

Fún àwọn aláfaramọ láti tá ọjà fún ọ

Rárá

A kìí pín

Àwọn ìbéèrè?

Lọ sí www.paxful.com

Ẹni tí a jẹ́

Tani ó ń pèsè àkíyèsi yíí?

Paxful jẹ́ olúpèsè ìfitónílétí Onípamọ́ àti pé ó wúlò fún àkántì Paxful tìrẹ.

N kàn tí a ń ṣe

Báwo ni Paxful ṣe ń dáàbòbò àlàyé ti ara ẹni mi?

Láti dáàbòbò àlàyé ti ara ẹni rẹ láti ìráyè sí àti lílò láìgbà àṣẹ, a lo àwọn ìgbésẹ̀ ààbò tí o ní ìbámu pẹlú òfín ìjọba àpapọ. Àwọn ìgbésẹ̀ wọnyí pẹlú àwọn ààbò kọmpútà àti àwọn fáìlì tó ní ààbò àti àwọn ilé.

Báwo ni Paxful ṣe ń gba àlàyé ti ara ẹni mi?

A gba àlàyé ti ara ẹni rẹ, fún àpẹẹrẹ, nígbàtí ìwọ

 • ṣí àkántì kan tàbí pèsè àlàyé àkántì
 • fún wa ní àlàyé olùbásọrọ tàbí ṣe ìfowóránṣẹ́ kan
 • lo àkántì Paxful rẹ láti fi àwọn owónàá ránṣẹ tàbí gbáà

A tún gba àlàyé ti ara ẹni láti ọdọ àwọn mííràn, gẹgẹ bí àwọn ilé-iṣẹ kírẹdítì, àwọn abánipolówó, àti àwọn ilé-iṣẹ mííràn.

Kíni ìdi tí èmi kò lé ṣe ìdópin gbogbo pínpín?

Òfin ìjọba àpapọ̀ fún ọ ní ẹtọ láti ṣe ìdópin nìkan

 • Pínpín fun àwọn abánipolówó wa ’àwọn ìdi ìṣòwò lójoojúmọ - àlàyé nípa títọ-kírẹ́dítì rẹ
 • àwọn abánipolówó láti lílo àlàyé rẹ láti ta ọjà fún ọ
 • pínpín fún àwọn aláfaramọ́ láti tá ọjà fún ọ

Àwọn òfin ìpínlẹ̀ àti àwọn ilé-iṣẹ kọọkan lè fún ọ ní àwọn ẹtọ ní àfikún láti ṣe ìdópin pínpín. Wo ìsàlẹ fún àlàyé sii lórí àwọn ẹtọ rẹ lábẹ òfin ìpínlẹ̀.

Àwọn àsọyé

Àwọn abánipolówó

Àwọn ilé-iṣẹ tí o jọmọ nípasẹ àjùmọ̀ni tàbí ìṣàkóso. Wọn lè jẹ ọ̀rọ̀-owó àti àwọn ilé-iṣẹ tí kìí ṣe tọ̀rọ̀-owó.

 • Àwọn abánipolówó wa pẹlú àwọn ile-iṣẹ lábẹ ìṣàkóso tó wọpọ tí Paxful Holdings, Inc.

Aláfaramọ́

Àwọn ilé-iṣẹ tí kò ní ìbátan nípasẹ àjùmọ̀ni tàbí ìṣàkóso. Wọn lè jẹ ọ̀rọ̀-owó àti àwọn ilé-iṣẹ tí kìí ṣe tọ̀rọ̀-owó.

 • Àwọn aláfaramọ́ pẹlú èyítí a pín àlàyé ti ara ẹni pẹlú àwọn olùpèsè iṣẹ tí o ṣe àwọn iṣẹ tàbi àwọn iṣẹ ní ìpó wa.

Àjùmọ̀tajà

Àdéhùn alákọọ́lẹ̀ buwọ́lù láàrín àwọn ilé-iṣẹ ìṣúná tí kò ní ìbátan tí ó parapọ̀ ta àwọn ọjà tàbí pèsè àwọn iṣẹ fún ọ.

 • Àwọn alájùmọ̀-tajà-papọ wa pẹlu àwọn ilé-iṣẹ ìṣúná.

Àlàyé pàtàkì mííràn

A lè fi àlàyé ti ara ẹni ránṣẹ́ sí àwọn orílẹ-èdè mííràn, fún àpẹẹrẹ, fún iṣẹ oníbárà tábí láti ṣàkóso àwọn ìdúnàádúrà.

California: Ti àkántì Paxful rẹ bá ní àdírẹ́ẹ̀sì ìfìwéránṣẹ California, a kò ní pín àlàyé ti ara ẹni tí a gbà nípa rẹ àyàfi sí iye tí a gbà láàyè lábẹ òfin California.

Vermont: Ti àkántì Paxful rẹ bá ní àdírẹ́ẹ̀sì Vermont kan, a kò ní pín àlàyé ti ara ẹni tí a gbà nípa rẹ pẹlú àwọn aláfaramọ́ àyàfi tí òfin bá gbà láàyè tàbí o pèsè àṣẹ.