Jọwọ dúró lákòkò tí à ń wá àwọn ìnájà tí ó dára jùlọ fún ọ.

Buy from

Sanwó pẹ̀lú

Price per Ethereum

Bíí ó ṣe Le Ra Ethereum lórí Paxful

Àwọn ìfọkansí Paxful láti mú ìfisípò owó dé ọ̀dọ̀ àwọn mílíọnù ti àwọn ẹnì-kọọkan tí kò ní báǹkì káàkiri àgbáyé. A jẹ kí ó rọrùn àti ààbò láti ṣe pàṣípààrọ owó rẹ tàbí àwọn Kọ́rẹ́ńsì-kírípítò mííràn fún Ethereum (ETH) àti lò ní ibití o nílò rẹ jùlọ, láti àwọn rírà lójoójúmọ si òwò aláìṣegbọ́kànlé.

Ibi Ìtajà ènìyàn-lagbára ti Paxful fàyè gbà ọ láti ra Ethereum tààrà láti ọdọ àwọn aṣàmúlò ní àgbáyé, láìsí báǹkì tàbí àwọn alágbàtà mííràn. Èyí ní bí o ṣe lè ra ETH lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀:

  1. Ṣẹdá àkántì kan – Wíwọlé láti gba wálẹ́ẹ̀tì onídíjítà ọfẹ kan níbi tí o lè fi ETH rẹ pamọ sí láìléwu.
  2. Ṣàwákiri àwọn ìnájà - Yan ìlànà ìsanwó ti o fẹ jùlọ, tẹ iye tí ìwọ yóò ná sí èyíkèyí kọ́rẹ́ńsì, àti lu Wá Àwọn ìnájà. Farabalẹ ṣe àtúnyẹwò àwọn àdéhùn ti ìnájà kọọkan kí o ṣàyẹwò aṣàpèjúwe ti olùtajà náà. Ṣe ìfojúsí pẹkípẹkí si àwọn òṣùwọn wọn, wíwà, àti àwọn ìjábọ̀ láti àwọn òwò tí o kọjá.
  3. Bẹ̀rẹ̀ ìdókòwò- Tí o bá ní ìtẹlọrùn pẹlú àwọn àdéhùn ìfẹnukò olùtajà náà, tẹ iye ti o fẹ ná àti kí o bẹrẹ òwò náà. Èyí yóò ṣíí ìtàkurọ̀sọ ojutaye nibi ti olùtajà yóò ti pèsè fún ọ ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àwọn ìtọ́sọ́nà. Tẹlé àwọn ìtọ́nísọ́nà ní gẹ́gẹ́ àti má ṣe ṣiyèméjì láti bèèrè èyíkèyí ìbéèrè.
  4. Gba ETH- Lẹ́yìn tí o fi owó sísan ránṣẹ àti sàmìsí òwò bí a ti sanwó, fún olùtajà ní àwọn àsìkò díẹ láti jẹ́rìsí ìdúnàádúrà náà. Lẹhinna wọn yóò fi ETH silẹ tààrà sínú wálẹ́ẹ̀tì Paxful rẹ.
  5. Fi ìjábọ̀ sílẹ̀ - Sọ fún wa àti àwọn aṣàmúlò mííràn nípa ìrírí rẹ pẹlú Olùbádòwòpọ̀ òwò rẹ. Èyí ṣe pàtàkì ní títọjú ìkànnì wa láìléwu fún gbogbo ènìyàn.

Wo bí àiléwu, ìyára, àti ìrọrùn tí o jẹ láti ra Ethereum láti Paxful? Pẹlú àwọn ìlànà ìsanwó 300 + láti yàn ninu, ìdókòwò kírípítò báyì kò ni wàhálà ninu rárà. Ṣàbẹwò sí Ibi àmúsọgbọ́n tàbí de ọdọ ẹgbẹ àtìlẹyìn wa fún àlàyé síwájú síi.

Pẹlú àwọn ìlànà ìsanwó tí ó ju 300 lọ láti sanwó pẹlú owó, àwọn ìfiránṣẹ́ báǹkì, àti àwọn káàdì ẹ̀bùn, ríra ETH kò rọrùn rárá. O kò rí ìlànà ìsanwó tí o fẹ jùlọ? Jẹ kí a mọ àti pé a yóò gbìyànjù láti ṣàfikún rẹ lórí ìkànnì wa. Fún àlàyé diẹ síí, ṣàyẹwò Ibi àmúsọgbọ́n wa tàbí kàn sí ẹgbẹ àtìlẹyìn wa.