Jọwọ dúró lákòkò tí à ń wá àwọn ìnájà tí ó dára jùlọ fún ọ.

Buy from

Sanwó pẹ̀lú

Price per Bitcoin

Bí o ṣe lè ra Bitcoin pẹ̀lú Venmo

Tí o bá fẹ́ ra Bitcoin ṣùgbọ́n ìwọ kò ní ọnà mííràn láti fi owó ránṣẹ́ tàbí ní ìyọnu nípa àṣírí, Venmo ni ọ̀nà ìsanwó tó dára jùlọ fún ọ. O rọrùn láti lò — ìwọ́ kàn ní láti gba áápù náà kí o sì so bánkì rẹ pọ̀ mọ́ àkántì Venmo rẹ.

Láti ra BTC pẹ̀lú Venmo, o kọ́kọ́ nílò láti forúkọsílẹ̀ fún wálẹ́ẹ̀tì Bitcoin ọ̀fẹ́ nípasè títẹ Ṣ'èdá àkántì. Ìwọ yóò tún nílò láti jẹ́rìísí ìdánimọ̀ rẹ fún wa kí o tó lè ra BTC.

Lẹ́yìn tí o wọlé, tẹ Ra Bitcoin kí o yan Venmo bíi ọ̀nà ìsanwó láti gbá àwọn ìnájà tí kò jọmọ́ọ jáde. A dábàá pé kí o ṣe àtúnyẹwò asàpèjúwe olùtajà láti ṣe ìwọ̀n ìfọkàntán wọn nípasẹ̀ títẹ orúkọ aṣàmúlò wọn láti rí ìtàn òwò wọn ati àwọn àtúnyẹwò láti ọ̀dọ̀ àwọn olùbádòwòpọ̀ àtẹ̀yìnwá.

Mú ìnájà tí o fẹ́ràn jùlọ julọ kí o tẹ láti wo àwọn àlàálẹ̀ òwò kí o sì bẹ̀rẹ̀ òwò náà. Ṣetán láti fi fọ́tò àdáyà sílẹ̀ níbi tí o ti mú Ìdánimọ̀ tí ó tọ̀nà dání tàbí àwòrán agbàwòrántán ti àkántì Venmo rẹ nígbàtí olùtajà bá bèrè. Owó rẹ ní ààbò ní ìpele yìí nípasẹ̀ ẹ́síkírò Paxful níbití a ti di Bitcoin olùtajà mú fún ìgbà díẹ̀ títí tí òwò yóò fi parí tàbí jẹ́ fífagilé.

Tẹ Ṣàmìsíi bíi Ti Sanwó ní kété tí o bá fi owó náà ránṣẹ́ láti àkántì Venmo rẹ kí o dúró de olùtajà láti fa Bitcoin rẹ kalẹ̀ láti ẹ́síkírò sínú wálẹ́ẹ̀tì Paxful rẹ. Òhun nìyẹn! Owó láti àkántì Venmo rẹ ti di Bitcoin báyìí.

Tí o bá ní ìjábọ̀ nípa ibi ìtajà wa tàbí fẹ́ gbé àríyànjiyàn dìde, ní òmìnira láti kàn sí ẹgbẹ́ àtìlẹ́yìn alábàárà wa. A wà lórí ayélujára nígbàkugbà, èyíkèyí ọjọ́ ti ọ̀sẹ̀ láti ṣé ìrànlọ́wọ́ fún ọ pẹ̀lú àwọn ìfiyèsí rẹ.