Jọwọ dúró lákòkò tí à ń wá àwọn ìnájà tí ó dára jùlọ fún ọ.

Buy from

Sanwó pẹ̀lú

Price per Bitcoin

Bí o ṣe lè ra Bitcoin pẹ̀lú PayPal

PayPal jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ètò ìfiránṣẹ́ owó orí ayélujára pàtàkì ní àgbáyé tí o ṣiṣẹ́ bíi àṣàyàn sí àwọn sọ̀wédowó àti àwọn ìbéèrè owó. Ó ń fúnni ní ọ̀nà ìfiránṣẹ́ àti gbígba owó káríayé tí ó rọrùn tí ó sì yára, àti àwọn ìlànà ìsanwó nígbàkugbà, níbikíbi.

Ríra Bitcoin pẹ̀lú PayPal lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ti ṣeéṣe ní báyìí lóri ibi ìtajà ẹnìkan-sí-ẹnìkejì ti Paxful. O lè wá àwọn ìnájà lọ́pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n gba PayPal gẹ́gẹ́ bíi ọ̀nà ìsanwó tí wọ́n yàn láàyò ní ìkànnì wa. Tí o kò bá rí ìnájà tí ó yẹ, o lè ṣẹ̀dà ti ara rẹ nígbà gbogbo láti fa àwọn aṣàmúlò tí wọ́n fẹ́ ṣòwò BTC nípa lílo PayPal mọ́ra.

Fún ìrírí ìdókoòwò tí ó ní ààbò síi, díẹ̀ nínú àwọn olùtajà lè nílò àwọn ìgbésẹ àfikún láti ṣ'àrídájú àwọn ìdánimọ̀ àwọn olùbádòwòpọ̀ wọn. Àwọn ìgbésẹ wọ̀nyí lè bèrè lọ́wọ́ rẹ láti ṣàfihàn àwọn ìwé àkọsílẹ̀ kan gẹ́gẹ́ bíi àwọn káàdì Ìdánimọ̀, àwọn fọ́tọ̀ àdáyà, àti / tàbí àwọn àwòrán agbàwòrántàn. Èyí dín eewu àwọn ìsanwó gbájúẹ̀ àti lílo àwọn àkántì PayPal láì gba àṣẹ, èyí tí yóò sọ Paxful di ibi ìtajà àìléwu.

Àwọn àdéhùn àti àwọn àlàálẹ̀ ìnájà lè yàtọ díẹ̀ láti ìnájà ọ̀kan sí òmííràn, nítorínáà ríi dájú pé o kà o sì faramọ́ àwọn ìbéèrè olùtajà ṣaájú kí o tó bẹ̀rẹ̀ òwò náà. O lè lo Ẹ̀rọ ìṣirò Bitcoin wa ti orí ayélujára láti gba ìdíyelé iye BTC tí o lè rà pẹ̀lú iye tí o ní ní kọ́rẹ́nsì tí o Yàn láàyò. Fún ìròyìn díẹ̀ síi, o tún le wo lílọ kiri fídíò wa ní kíkún lóri bí o ṣe lè ra Bitcoin pẹ̀lú Paypal lóri Paxful.

Ní Paxful níbí, a ní ìfọkànsí láti ṣe ọ̀nà tí ìwọ́ ń gbà yí àwọn owó PayPal rẹ padà sí Bitcoin ní ìrọ̀rùn pẹ̀lú ibi ìtajà ẹnìkan-sí-ẹnìkejì wa tí ó ní ààbò tí ó sì jẹ́ ọ̀rẹ́ aṣàmúlò. Wá òwò tí ó dára jùlọ fún ọ lónìí.