Jọwọ dúró lákòkò tí à ń wá àwọn ìnájà tí ó dára jùlọ fún ọ.

Rà Láti

Sanwó pẹ̀lú

Òṣùwọn fún Bitcoin

Bí o ṣe lè ra Bitcoin pẹ̀lú Cash App

Cash App jẹ́ wálẹ́ẹ̀tì orí ayélujára àti áàpù ìsanwó tí ó fún ọ láàyè láti gbà àti fi owó ránṣẹ́ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ sí ẹbí àti àwọn ọ̀rẹ́. Ó tún fún ọ láàyè láti gba ìsanwó alágbèéká àti ti káàdì fún ìṣòwò rẹ kí o sì f'owó ránṣẹ́ sí àkántì bánkì rẹ.

Lóri ibi ìtajà ẹnìkan-sí-ẹnìkejì Paxful, ìwọ́ lè wá ra Bitcoin pẹ̀lú Cash App. Kàn tẹ̀lé àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí láti gba BTC rẹ:

  1. Wọlé sí Paxful – Wọlé sí àkántì Paxful rẹ tàbí ṣ'èdá tuntun mííràn. Fíforúkọṣílẹ̀ lóri Paxful fún ọ ní ẹ̀tọ́ láti ní wálẹ́ẹ̀tì Bitcoin tí kò ní owó àfikún lórí.
  2. Yan ìlànà ìsanwó rẹ - Mú Cash App bíi ìlànà ìsanwó láti mú àtòkọ gbogbo àwọn ìnájà tí wọ́n gba ìlànà ìsanwó yìí wá. O tún lè tẹ iye tí o ṣetán láti ná láti ṣa àwọn ìnájà tí kò jọ mọ́ọ jáde. Ǹjẹ́ o fẹ́ mọ iye ní Bitcoin tí ìwọ yóò gbà? Gbìyànjú Ẹ̀rọ ìṣirò Bitcoin wa.
  3. Wá ìnájà kan tó dára – Ṣàwákiri àtòkọ àwọn ìnájà kí o sì ríi dájú láti ṣe àyẹ̀wò abẹ́lẹ̀. Wo wíwà, àwọn ìṣirò ìgbayìsí, ìtàn ìṣòwò ti olùtajà, àti irú àwọn àwòṣe mííràn ṣe. Lọ́gán tí o bá rí ìnájà tí ó dára tí ó dàbí wípé ó tẹ́ ọ lọ́rùn, ṣe àtúnyẹ̀wò àwọn àdéhùn olùtajà fínnífínní ṣaájú kí o tó bẹ̀rẹ̀ òwò náà.
  4. Faramọ́ àwọn àdéhùn náà kí o sì bẹ̀rẹ̀ òwò – Nígbàtí o bá ń ra Bitcoin pẹ̀lú Cash App, máa gbáradì $Cashtag àti ẹ̀rí ìsanwó rẹ ní ìgbàgbogbo láti ṣàrídájú ìdúnadúrà tó lọ geere. Díẹ̀ nínú àwọn olùtajà lè tún fẹ́ kí o fi ẹ̀dà káàdì Ìdánimọ̀ rẹ àti àwọn ìwé àkọsílẹ̀ mííràn láti jẹ́rìísí ìdánimọ̀ rẹ. Nítorínáà múra sílẹ̀ fún irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀. Lọ́gán tí òwò náà bá bẹ̀rẹ̀, tẹ̀lé àwọn ìtọ́nisọ́nà láti ọ̀dọ̀ olùtajà. Ṣe àkíyèsí pé Paxful lo ètò ẹ́síkírò kan tí yóò mú Bitcoin olùtajà dúró títí tí ìdúnadúrà yóò fi parí láti dáàbò bò ọ́ kúrò lọ́wọ́ àwọn atannijẹ tí ó ṣeéṣe. Lọ́gán tí òwò náà bá ti parí ní àṣeyọrí, ìwọ yóò gba Bitcoin náà tààrà ní wálẹ́ẹ̀tì Paxful rẹ.

Ní Paxful níbí, a jẹ́ kí ó rọrùn tí kò sì ní ewu láti ra BTC pẹ̀lú Cash App. Láti kẹ́kọ̀ọ́ síi nípa ríra Bitcoin lóri ìkànnì wa, ní òmìnira láti wo Ibi Àmúsọgbọ́n wa tàbí kàn sí ẹgbẹ́ àtìlẹ́yìn wa.