Ìlànà Ẹ̀bùn Atọ́ka Àṣìṣe/Ọlọ́jẹ̀

Paxful, Inc. (tún tọka sí bí "Paxful," "àwa," "wa," tàbí "tiwa") gbé gbogbo àwọn ìgbésẹ ti a nílò láti dáábòbò ìpamọ́ rẹ. Nínú Ìlànà Kúkì yíí (“Ìlànà”), gbé àwọn ìgbésẹ láti mú ọjà wa dára síi àti pèsè àwọn ọnà àbáyọ tó ní ààbò fún àwọn oníbárà wa. Nínú Ìlànà Ẹ̀bùn Atọ́ka Àṣìṣe/Ọlọ́jẹ̀ ("Ìlànà"), a ṣe àpèjúwe àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó tọ̀nà fún Ètò Ẹ̀bùn Atọ́ka Àṣìṣe/Ọlọ́jẹ̀ wa àti bí o ṣe yẹ kí o lo ní àsopọ pẹ̀lú lílò wẹ́búsáìtì wa ní https://paxful.com/ , pẹ̀lú, ṣùgbọ́n kìí ṣe òpin sí, Wálẹ́ẹ̀tì Paxful, ìkànnì ìdókowò Bitcoin lórí ayélujára, áàpù ẹ̀rọ alágbèéká, àwọn ojú-ìwé ìgbóhùnsáfẹ́fẹ́ àwùjọ, tàbí àwọn ohun-ìní àti iṣẹ́ orí ayélujára mííràn (lapapọ, “Wẹ́búsáìtì ” náà), tàbí nígbàtí o bá lo èyíkèyí àwọn ọjà, àwọn iṣẹ́, àkóónú, àwọn ẹyà, ìmọ-ẹrọ, tàbí àwọn iṣẹ́ tí a ńṣe (lápapọ, “Àwọn Iṣẹ́”náà). A ṣe àgbékalẹ Ìlànà yíí láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ìwọ láti gbà àlàyé nípa bíí o ṣe lè ṣe kópa nínú Ètò Ẹ̀bùn Atọ́ka Àṣìṣe/Ọlọ́jẹ̀ wa, èyítí àwọn àbájáde ìwádìí aláàbò tọ̀nà, àti àwọn ànfàní wo ní o lè gbà. Jọ̀wọ́ ṣe àkíyèsi pé àwọn iṣẹ́ tí a pèsè lè yàtọ̀ nípa agbègbè.

Fún gbogbo àwọn ìdí, ẹ̀yà èdè Gẹ̀ẹ́sì ti ìlànà ẹ̀bùn atọ́ka àṣìṣe/ọlọ́jẹ̀ yíí yóò jẹ ògidì, ohun-èlò ìṣàkóso. Ní ìṣẹlẹ ti èyíkèyí èdè-àìyedè láàrín ẹ̀yà èdè Gẹ̀ẹ́sì lórí ìfitónílétí Onípamọ́ yíí àti èyíkèyí ìtumọ àtẹlè sí èyíkèyí èdè mííràn, ẹ̀yà èdè Gẹ̀ẹ́sì yóò ṣàkóso àti darí.

Kíni Ètò Ẹ̀bùn Atọ́ka Àṣìṣe/Ọlọ́jẹ̀?

Láti lè mú ìlọsíwájú bá Paxful àti Àwọn iṣẹ́ rẹ, Ètò Ẹ̀bùn Atọ́ka Àṣìṣe/Ọlọ́jẹ̀ Paxful pèsè fún àwọn aṣàmúlò wa ní àyè láti gba ẹ̀bùn kan fún ìṣèdámọ̀ àwọn ìṣòro ìmọ̀-ẹ̀rọ.

Báwo ni ìwọ ṣe lè sọ àwọn àwárí Ètò Ẹ̀bùn Atọ́ka Àṣìṣe/Ọlọ́jẹ̀ fún wa?

Gbogbo irú àwọn ìbáraẹnisọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ yẹ kí ó jẹ́ dídarí sí [email protected] . Nínú ìfisílẹ̀ rẹ jọ̀wọ́ ṣàlàyé àpèjúwe kíkún àìlágbára àti ẹ̀rí tó dájú pé àìlágbára wà (àlàyé / àwọn ìgbésẹ láti tún ṣe / àwọn agbàwòrántán / àwọn fídíò / àwọn ìwé àfọwọ́kọ tàbí irú àwọn ohun èlò mííràn).

Àwọn òfin Ètò

Irúfin èyíkèyí àwọn òfin wọ̀nyí lè já sí àìníkópa fún ẹ̀bùn kan.

 • Ìdánwò àwọn ìpalára kàn takò àkántì tí ìwọ ni tàbí àwọn àkántì tí ìwọ ní ìmọ̀ sí láti ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ni àkántì náà láti ṣe ìdánwò takò.
 • Máṣe lo wíwá kan láti fi ẹnukò / yọ dátà jáde tàbí gbára lé àwọn ètò mííràn. Lo ẹrí ti ìmọràn nìkan láti ṣe àfihàn ìṣòro kan.
 • Tí àlàyé tí ó ní ìfura gẹ́gẹ́bí àlàyé àdáni, àwọn ìwé ẹ̀rí, àti bẹẹbẹẹ lọ .. ti wọlé bí apákan ti ìpalára kan, kò gbọdọ wà ní fífipamọ, títọjú, ti firánṣẹ́, wọlé sí, tàbí bíbẹ́ẹ̀kọ́ ti ṣaáyan lẹyìn ìṣàwárí àkọkọ.
 • Àwọn oníwadì lè má ṣe, àti pé a kò fún ni àṣẹ láti ṣe èyíkèyi iṣẹ́ ti yóò jẹ ìdàmú, ìbàjẹ́ tàbí ìpalára fún Paxful.
 • Àwọn oníwadì lè má ṣàfìhàn àwọn ìpalára ní gbangba (pínpín èyíkèyí àwọn àlàyé ohunkóhun ti ẹnikẹni mííràn ju àwọn òṣìṣẹ́ Paxful ti a fún ní àṣẹ), tàbí bíbẹ́ẹ̀kọ́ pín àwọn ìpalára pẹ̀lú ẹnìkẹta, láìsí ìgbaniláàyè mímọ̀ sí ti Paxful.

Báwo ni a ṣe ńṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìṣòro tí a dámọ̀ lábẹ́ Ètò Ẹ̀bùn Atọ́ka Àṣìṣe/Ọlọ́jẹ̀?

Gbogbo àwọn àwárí ni a ṣàgbéyẹ̀wò nípa lílò ọnà tí ó dá lórí eewu.

Àdéhùn Àìṣàfihàn

Ṣáájú kí á tó bẹrẹ ìjíròrò èyíkèyí àwọn àlàyé tí ìwọ ní ìbátan sí àwọn ìṣòro tí a fi ìdí rẹ múlẹ tí ìwọ ti dámọ̀ lábẹ́ Ètò Ẹ̀bùn Atọ́ka Àṣìṣe/Ọlọ́jẹ̀, pẹ̀lú ìsanpadà, àti bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ lọ, ìwọ yóò nílò láti wọ inú Àdéhùn Àìṣàfihàn pẹ̀lú wa.

Báwo ni a ṣe ń san àwọn èrè Ètò Ẹ̀bùn Atọ́ka Àṣìṣe/Ọlọ́jẹ̀?

Paxful ni ó má ń san gbogbo àwọn èrè bẹ́ẹ̀. Gbogbo àwọn èrè ni a lè san tí kò bá ṣe pé wọn tako àwọn òfin àti ìlànà tó wà fún un, pẹ̀lú ṣùgbọ́n kìí ṣe òpin sí àwọn ìjẹniníyà òwò àti àwọn ìhámọ ọrọ̀ ajé.

Ìgbà wo ni yóò gbà wá láti ṣe ìtúpalẹ̀ àwọn àwárí Ètò Ẹ̀bùn Atọ́ka Àṣìṣe/Ọlọ́jẹ̀ rẹ?

Nítorí ìyàtọ àti ẹdá ti ó nira ti àwọn ìṣòro ìmọ̀-ẹ̀rọ, a kò tíì ṣètò àwọn àkókò pàtàkì kan fún ìtúpalẹ̀ àwọn àwárí lábẹ́ Ètò Ẹ̀bùn Atọ́ka Àṣìṣe/Ọlọ́jẹ̀. Àtúpalẹ̀ wa ti parí nikan nígbatí a bá jẹ́rìsí wíwà tàbí àìsí ti ìpalára kan.

Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ wo ni a yọ kúrò nínú Ètò Ẹ̀bùn Atọ́ka Àṣìṣe/Ọlọ́jẹ̀?

Àwọn ìpalára kan ni a kà sí aláìláàyè fún Ètò Ẹ̀bùn Atọ́ka Àṣìṣe/Ọlọ́jẹ̀. Àwọn ìpalára wọnyí tí kò ní ààyè pẹ̀lú, ṣùgbọ́n kìí ṣe òpin sí:

 • Ímeèlì-àìbéèrè
 • Àwọn ìpalára tí ó nílò ìtannijẹ gba àlàyé ẹni / jìbìtì àlàyé àdáni;
 • Àwọn ìkọlù DDOS;
 • Àwọn ìṣòro aláìlálàyé kíkún tí kò ní ipa fún ṣíṣe;
 • Àwọn ìpalára ààbò ní àwọn áápù ẹnìkẹta àti lórí àwọn wẹ́búsáìtì ẹnìkẹta tí a ṣepọ̀ pẹ̀lú Paxful;
 • Àbájáde scanner tàbí àwọn ìjábọ̀ tí a gbà láti inú scanner;
 • Àwọn ìdojúkọ tí a rí nípasẹ ìdánwò àdáṣe;
 • Àwọn àṣìṣe inú sọfitiwia tí a tújáde ní gbangba sí sọfitiwia Intanẹẹti láàrín àwọn ọjọ 30 ti ìṣàfihàn wọn;
 • Àwọn àjálù oníjìbìtì láàrín áápù àti aṣàmúlò
 • Host header injections láìsí pàtó kan, ipa tí o ṣeé fihàn
 • Self-XSS, èyítí ó pẹ̀lú èyíkèyí àlàyé ògidì tì olùfaragbá tẹ̀ sí;
 • Wọlé/jáde CSRF;

Alààyè síwájú sí

Tí o bá ń wá àlàyé síwájú síi nípa Ìlànà yíí, ìwọ lè kàn sí wa nípasẹ ímeèlì [email protected] .