Ìlànà AML

Paxful, Inc. àti Paxful USA, Inc. (ni ọkọ̀ọ̀kan àti ní àpapọ̀, “Ilé-iṣẹ́” náà), tí a dàpọ̀ lábẹ àwọn òfin ti Ìpínlẹ̀ ti Delaware ń pèsè àwọn iṣẹ́ nípasẹ́ ibi ìtajà ẹnìkan-sí-ẹnìkejì tí ó ní agbára Íńtánẹ́ẹ̀tì (“P2P”) fún rírà àti títà àwọn dúkìá onídíjítà.

Ilé-iṣẹ́ náà ti forúkọsílẹ̀ bí Ìṣòwò Àwọn iṣẹ́ Owó pẹ̀lú Nẹ́tìwọọ̀kì Ìfipámúni Irúfin ìṣúná ti Ẹka Ìṣúra ti Amẹ́ríkà (“FinCEN”). Awọn ìlànà àti ìgbésẹ̀ Paxful ti Ìgbógun ti-gbígbé Owó lọ́nà Àìtọ́ (“AML”) ni a ṣe láti ṣe ìdíwọ́ àwọn iṣẹ́ ṣíṣe arúfin lórí ìkànnì, dáàbòbò àwọn aṣàmúlò, ìṣòwò, àti àwọn kọ́rẹ́ńsì onídíjítà àti àwọn agbègbè àwọn iṣẹ́ ìṣúná láti ìlòkulò nípasẹ àwọn ọ̀daràn. Ilé-iṣẹ́ náà wà ní ìbámu pẹ̀lú àwọn ìbéèrè ti Òfin Ìkọ̀kọ̀ Báǹkì àti àwọn ìlànà àti ìtọ́sọ́nà tí ó jọmọ FinCEN.

Gẹ́gẹ́bí apákan ti àwọn ìlànà Ìbámu Paxful, Àwọn ìlànà Mọ Oníbárà Rẹ (“KYC”) àti àwọn ìlànà fún ẹni kọ̀ọ̀kan àti àwọn oníbárà ilé-iṣẹ́ ti ṣètò láti jẹ kí Ilé-iṣẹ́ ṣe àgbékalẹ ìgbàgbọ tí ó bọ́gbọ́nmu pé o mọ ìdánimọ̀ òtítọ́ ti àwọn ti àwọn oníbárà rẹ fún irú àtúnyẹwò bẹ́ẹ̀ ti jẹ́ ṣíṣe. Ìlànà náà kan sí gbogbo àwọn aṣàmúlò lórí ìkànnì àti pé gbogbo àwọn òṣìṣẹ ti Ilé-iṣẹ́ tẹ́le, àwọn alámọràn, àwọn olórí, àwọn oníwun àti àwọn olùdarí.

Lílo ọnà orísun eewu gẹ́gẹ́bí apákan ti ìjẹ́rìísí KYC & AML, Paxful ti ṣe àwọn ìgbésẹ̀ wọ̀nyí:

  • Ìgbàsíṣẹ́ Olórí Òṣìṣẹ́ Ìbámu tí ó ní ìpele ìkọ́ṣẹ́mọṣẹ́ àti òmìnira tó yẹ, ní ojúṣe fún àbojútó ti ìbámu pẹ̀lú òfin tí ó yẹ, àwọn ìlànà, àwọn òfin àti ìtọ́sọ́nà ilé-iṣẹ́;
  • Ṣíṣètò àti ṣètọjú orísun KYC tí ó ní eewu, Àìṣèmẹ́lẹ́ Àìjáfara Oníbárà (CDD), àti Ìlànà Àìṣèmẹ́lẹ́ Àìjáfara Amúdárasi (EDD);
  • Ṣíṣètò àwọn Ìpele tí ó dá lórí eewu fún Ìjẹ́rìísí ti àwọn aṣàmúlò Ilé-iṣẹ́ ( tọ́ka sí èyí Ìfìwéránṣẹ́ búlọ́ọ̀gì);
  • Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìbéèrè agbófinró àti àwọn ìbéèrè ìlànà agbègbè;
  • Ṣíṣe ìforúkọsílẹ̀ ti Àwọn Ìjábọ̀ Iṣẹ́ Ìfura (“SARs”);
  • Ìkẹ́kọ̀ BSA / AML / OFAC jákèjádò ilé-iṣẹ́;
  • Lílo oríṣiríṣi àwọn ọnà ẹrọ ìgbógun ti-jìbìtì;
  • Òfin tí ńlọ lọwọ tí ó dá lórí bíbójútó ìdúnàádúrà;
  • Àwọn ìwádìí nípa lílo àwọn àtúpalẹ̀ àkópọ̀ ìtẹ̀léra Kírípítò;

A yóò kọ̀wé ránṣẹ́ sí SARs tí a bá mọ, fura tàbí ní ìdí láti fura àwọn iṣẹ́ ìfura ti ṣẹlẹ̀ lórí ìkànnì wa. Ìdúnàádúrà ìfura kan jẹ ìgbàgbogbo èyítí ó ńṣe ségesège pẹ̀lú ìṣòwò ti aṣàmúlò tí a mọ àti ti òfin, àwọn iṣẹ́ ti àdáni tàbí àwọn ọnà ti ara ẹni. Olórí Òṣìṣẹ́ Ìbámu wa ṣe àtúnyẹwò àti ṣe ìwádìí iṣẹ́ ìfura láti pinnu bóyá a ti gba àlàyé tí ó tó láti ṣe àlàyé ìfìwéránṣẹ́ ti SAR kan. Olórí Òṣìṣẹ́ Ìbámu wa ṣètọjú àwọn ìgbàsílẹ àti àwọn ìwé àtìlẹyìn ti gbogbo àwọn SAR tí a ti fìwéránṣẹ́ sí.

Ilé-iṣẹ́ náà tún ti gba àwọn ìlànà ìjẹníyà OFAC ti ńlọ lọ́wọ́ àti àwọn ìlànà tí a ṣe ṣètò láti dáàbòbò ìkànnì láti lóò fún àwọn ìdúnàádúrà tí a kọ̀ leewọ̀, nípasẹ àwọn ènìyàn tí a jẹníyà tàbí fún àwọn ìdí ti yíyẹra fún, yàgò fún tàbí bíbẹ́ẹ̀kọ́ tí rírékọjá Amẹ́ríkà àti àwọn ìjẹníyà àgbáyé.

Paxful ṣe ìfọwọ́sowọ́pọ̀ ní kíkún pẹ̀lú gbogbo OFAC, Àwọn orílẹ-èdè Ti a Ṣáṣáyàn pàtàkì (SDN) àti àwọn àtòkọ àwọn èèyàn tí a dínà mọ. Jọ̀wọ́ tọka sí àtẹ̀lé Ìtọ́kasí fún àtòkọ Ilé-iṣẹ ti àwọn orílẹ-èdè tí ó dá lórí eewu tí a gbẹ́sẹ̀lé tí ó ní ìdíwọ láti lo ìkànnì Paxful.

Níbi tí Paxful ti pèsè fún ìwọ ìtumọ̀ ti ẹ̀yà èdè Gẹ̀ẹ́sì ti ìlànà yii, lẹ́hìnnà ìwọ gbà pé a pèsè ìtumọ̀ fún ìrọ̀rùn rẹ nìkan àti pé àwọn ẹ̀yà ède Gẹ̀ẹ́sì ti ìlànà náà yóò ṣàkóso ìbáṣepọ̀ rẹ pẹ̀lú Paxful. Tí ìtakò èyíkèyí bá wà láàrín ohun tí ẹ̀yà ẹ̀dè Gẹ̀ẹ́sì ti ìlànà náà sọ àti èyítí ìtumọ̀ kan sọ, lẹ́hìnnà ẹ̀yà èdè Gẹ̀ẹ́sì yóò ṣàkóso.