The Affiliate Program has been temporarily paused as we make changes to create a fair and sustainable program for the Paxful community. Learn more here.

Ìfẹnukò Ìlò Ètò Ìbánipolówó

Ọjọ́ tí yóò bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́: Ọ̀wàrà (October) 21, 2019

O ṣeun tí ìwọ́ forúkọsílẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ọmọ ẹgbẹ́ Ètò Ìbánipolówó Paxful. Àlàyé tí o pèsè fún Paxful bíi ara ìgbésẹ̀ ìforúkọsílẹ̀ ní Paxful yóò fi pamọ́ tí yóò sì ṣ'àmójútó ní ìbámu pẹ̀lú Ìlànà Ààbò Dátà Gbogboògbò ti European Union ("GDPR"). Ìwọ́ tẹ́wọ́gba Ìlànà Ìpamọ́ ìbámu-GDPR ti Paxful bíi ara ìgbésẹ̀ ìforúkọsílẹ̀ Ìbánipolówó náà.

Ní ìtẹ̀síwájú láti máa lo wẹ́búsaìtì Paxful (bóyá bíi Abánipolówó tàbí ìdàkejì), a yóò ríi gẹ́gẹ́ bíi wípé ìwọ́ ti gba o sì ti tẹ́wọ́gba Ìlànà Ìpamọ́, pẹ̀lú bí ó ṣe lè jẹ́ túntúnṣe, fífikún, tàbí pípààrọ̀ ní òrèkóòrè. Ẹ̀yà Ìlànà Ìpamọ́ tí à ń lò lọ́wọ́ ní ìwọ́ lè rí láti abala-ilé sáìtì yìí tàbí nípasẹ̀ títẹ ìtọ́kasí yìí: https://paxful.com/privacy. Láti yàgò fún iyèméjì, jọ̀wọ́ mọ̀ wípé àwon àlàyé àkántì kan lè jẹ́ pínpín pẹ̀lú àwọn Àpèwárajà rẹ bíi ara ìkópa rẹ níbi Ètò Ìbánipolówó, pẹ̀lú ṣùgbọ́n tí kò d'ópin sí àlàyé àgbègbè àti ìṣe àkántì.

Àwọn ìwọ̀nyí ni àwọn Àdéhùn àti Àlàálẹ̀ tó nííṣe pẹ̀lú Ètò Ìbánipolówó. Paxful ní àṣẹ ( ní ìfẹ́-inú àdáni àti pátápátá àti láì sí ìfitónilétí tẹ́lẹ̀) láti: (a) yí èyíkèyí tàbí gbogbo àwọn Àdéhùn àti Àlàálẹ̀ yìí padà, ní ìgbàkíìgbà àti ní òrèkóòrè, pẹ̀lú (sùgbọ́n tí kò d'ópin sí) àyípadà àwọn ìdá ọgọ́rún ìsanwó jáde owó-èrè bí a ṣe ṣàpèjúwe sí abẹ́, (b) dá dúró tàbí fagilé Ètò Ìbánipolówó náà, àti/tàbí (c) dá dúró tàbí dá iṣẹ́ Ìbánipolówó àti àkántì Paxful rẹ dúró pátápátá tí ìwọ́ bá kópa nínú àwọn ìwà kan bí a ṣe ṣàpèjúwe sí ìsàlẹ̀.

Gẹ́gẹ́ bíi Abánipolówó, ìwọ́ ní anfààní láti ṣàfihàn àwọn ẹnìkẹta sí Ibi Ìtajà Bitcoin Paxful àti kí o pa àwọn owó-èrè èyí tó dá lórí àwọn òwò BTC wọn tí wọ́n ṣe lórí ìkànnì wa. Paxful maá ń san gbogbo àwọn òwò-èrè Ìbánipolówó ní BTC nìkan.

Ètò Ìbánipolówó náà ni a ṣèto rẹ̀ ní ètò ìpele-méjì fún àwọn aṣàmúlò ẹnìkẹta ìgbà àkọ́kọ́ nìkan:

  • Ìpele 1 Àpèwárajà
    Àpèwárajà Ìpele 1 jẹ́ ẹnìkẹta tó forúkọsílẹ̀ láti lo Ibi Ìtajà Bitcoin Paxful nípasẹ̀ lílo ìtọ́kasí ìforúkọsílẹ̀ tó dá yàtọ̀ tí Paxful pèsè fún ìwọ nígbàtí o forúkọsílẹ̀ pẹ̀lú Ètò Ìbánipolówó.
  • Ìpele 2 Àpèwárajà
    Àpèwárajà Ìpele 2 jẹ́ ẹnìkẹta tó forúkọsílẹ̀ láti lo Ibi Ìtajà Bitcoin Paxful nípasẹ̀ lílo ìtọ́kasí ìforúkọsílẹ̀ tó dá yàtọ̀ tí Paxful kò bá ti pèsè fún Àpèwárajà Ìpele 1 tìrẹ.

Àwọn owó-èrè tó ṣeé san.

Àfi tí Paxful bá f'ọwọ́ sí ìdàkejì, ìwọ yóò pa owó-èrè láti ọ̀dọ̀ Paxful ní gbogbo ìgbà tí Àpèwárajà Ìpele 1 tàbí Àpèwárajà Ìpele 2 tìrẹ bá parí ìdúnadúrà "Ìrà" BTC nipasẹ̀ lílo Paxful.

Bí ìwọ́ ti mọ̀, Paxful ma ń gba Owósan Ẹ́síkírò ní ìbáṣepọ̀ pẹ̀lú òwò kọ̀ọ̀kan tí o parí lórí ìkànnì rẹ̀. Owósan Ẹ́síkírò náà lè yí padà láti ọwọ́ Paxful ní ìgbàkígbà àti ní ìgbà sí ìgbà. Ìwọ́ lè rí àlàyé Owósan Ẹ́síkírò àti iye rẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́ nípasẹ̀ títẹ ìtọ́kasí yìí: https://paxful.com/support/en-us/articles/360013609793-Paxful-fees

  • Nígbàtí Àpèwárajà Ìpele 1 bá parí ìdúnadúrà "Ìrà" BTC ní àṣeyọrí nípasẹ̀ lílo Paxful, Paxful yóò kírẹ́díìtì Wálẹ́ẹ̀tì Abánipolówó rẹ pẹ̀lú iye (ní BTC) tó ṣe déédé 50% Owósan Ẹ́síkírò tó ń ṣiṣẹ́ nígbà náà.
  • Nígbàtí Àpèwárajà Ìpele 2 bá parí ìdúnadúrà "Ìrà" BTC ní àṣeyọrí nípasẹ̀ lílo Paxful, Paxful yóò kírẹ́díìtì Wálẹ́ẹ̀tì Abánipolówó rẹ pẹ̀lú iye (ní BTC) tó ṣe déédé 10% Owósan Ẹ́síkírò tó ń ṣiṣẹ́ nígbà náà.
  • Ṣùgbọ́n, tí Àpèwárajà Ìpele 1 rẹ bá ṣe ìdúnadúrà "Ìrà" BTC pẹ̀lú Àpèwárajà Ìpele 1 ti ọmọ ẹgbẹ́ Ètò Ìbánipolówó mííràn, nígbà náà ọ̀kọ̀ọ̀kan nínu yín àti ọmọ ẹgbẹ́ mííràn yóò pín owó-èrè 50% ní déédé.
  • Bákannáà, tí Àpèwárajà Ìpele 2 rẹ bá ṣe ìdúnadúrà "Ìrà" BTC pẹ̀lú Àpèwárajà Ìpele 2 ti ọmọ ẹgbẹ́ Ètò Ìbánipolówó mííràn, nígbà náà ọ̀kọ̀ọ̀kan nínu yín àti ọmọ ẹgbẹ́ mííràn yóò pín owó-èrè 10% ní déédé.
  • Ìgbàkígbà tí ìwọ́ bá ń rà láti ọ̀dọ̀ tàbí tà fún ọ̀kan lára Àpèwárajà Ìpele 1 tàbí Àpèwárajà Ìpele 2 rẹ o kò ní pa owó-èrè kankan.

Owó-èrè rẹ tí o pa ní àsopọ̀ mọ́ èyíkèyí ìdúnadúrà bẹ́ẹ̀ ní a yóò sábà máa kírẹ́díìtì sí Wálẹ́ẹ̀tì Abánipolówó rẹ ní kíákíá bí ìdúnadúrà bẹ́ẹ̀ bá ṣe parí ní àṣeyọrí. Gbogbo ìgbà tí ìdúnadúrà bẹ́ẹ̀ bá parí ní àṣeyọrí, Paxful yóò fi ímeèlì ìṣàrídájú ránṣẹ́ sí ìwọ. Ní ọ̀nà yìí, ìwọ́ lè wo àṣẹ́kù owó Wálẹ́ẹ̀tì Abánipolówó rẹ bí yóò ṣe dàgbà láàrin dásíbọọdù Paxful rẹ.

Ní àwọn àyídàyidà tó dájú, ìwọ́ lè tún yẹ láti pa owósan àpèwárajà ní gbogbo ìgbà tí Àpèwárajà Ìpele 1 tàbí Àpèwárajà Ìpele 2 tìrẹ bá parí ìdúnadúrà "Ìtà" BTC nípasẹ̀ lílo Paxful. Láti mọ bí ìwọ́ bá ṣe yẹ láti pa àwọn owósan lórí àwọn ìdúnadúrà "Ìtà" Àpèwárajà Ìpele 1 àti Àpèwárajà Ìpele 2 rẹ, jọ̀wọ́ kàn sí Àtìlẹ́yìn Paxful ní [email protected]. Paxful ní ẹ̀tọ́ láti pinnu, nínú ìfẹ́ inú àdáni rẹ, bóyá a lè f'àyè gba ìwọ tàbí a lè má f'àyè gbà ọ́ láti pa èyíkèyí àwọn owósan àpèwárajà fún àwọn ìdúnadúrà "Ìtà".

Ṣíṣe Ìgbàjáde Àwọn Owó-Èrè Rẹ.

Gbogbo ìgbà tí àṣẹ́kù owó tó wà ní Wálẹ́ẹ̀tì Abánipolówó rẹ bá dé ó kéré jù US$10 ( ní iye BTC ní ìgbà yẹn), ìwọ yóò le fi gbogbo àṣẹ́kù owó náà ránṣẹ́ sí Wálẹ́ẹ̀tì BTC Paxful rẹ. Lọ́gán tí àṣẹ́kù owó Wálẹ́ẹ̀tì Abánipolówó rẹ bá dé àpapọ̀ iye ayérayé $300, ìwọ yóò nílò láti fi ìjẹ́rìísí ìdánimọ̀ àti àdírẹ́ẹ̀sì sílẹ̀. Lọ́gán tí o bá ti ṣe èyí, o ní òmìnira láti ṣe ohunkóhun tó wu ìwọ pẹ̀lú àwọn owópa rẹ. Láti pèsè èyí fún wa tàbí èyíkèyí àlàyé mííràn tí a lè nílò, ìwọ́ ṣ'àrídájú wípé òtítọ́ ni gbogbo àlàyé náà, ó ṣe déédé kò sì ṣinilọ́nà. Ìwọ́ gbà láti máa ṣe ìmúdójúìwọ̀n wa kíákíá tí èyíkèyí nínú àwọn àlàyé tí o pèsè bá yí padà. Ìwọ́ fún wa ní àṣẹ láti ṣe àwọn ìbéèrè, bóyá tààrà tàbí nípasẹ̀ àwọn ẹnìkẹta, tí a bá rò pé ó nílò láti jẹ́rìí sí ìdánimọ̀ rẹ tàbí dáàbò bo ìwọ àti/tàbí àwa kúrò lè jìbìtì tàbí ìrúfin ìnáwó mííràn, àti láti ṣe ìgbésẹ̀ tí a rò pé ó nílò èyí tó dá lórí àwọn àbájáde àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀. Tí a bá ṣe àwọn ìbéèrè yìí, o gbà o sì f'ọwọ́ síi wípé àlàyé àdáni rẹ lè jẹ́ ìfihàn sí ìtọ́kasí kírẹ́díìtì àti ìdènà jìbìtì tàbí àwọn àjọ ìrúfin ìnáwó àti wípé àwọn àjọ yìí lè fèsì sí àwọn ìbéèrè wa ní kíkún.

Pro Tip: A dábàá títa àwọn owópa BTC rẹ lóri ìkànnì wa fún àlékún èrè.

Àwọn Ìgbésẹ̀ tí a kọ̀

Èyí jẹ́ àtòkọ aṣojú (sùgbọ́n kò tíì parí) gbogbo irú àwọn ìwà àti àwọn ìṣesí tó lè mú Paxful (bí Paxful bá ti pinnu ní ìdájọ àdáni rẹ̀) kò (a) fagilé tàbí gba ìsanwó àwọn owó-èrè rẹ tí o pa tẹ́lẹ̀ (bóyá o tí gbàá jáde tàbí bẹ́ẹ̀ kọ̀) padà, àti/tàbí (b) dá Ìbánipolówó àti àwọn àkántì Paxful rẹ dúró tàbí dá'ṣẹ́ wọn dúró.

  • Lílo àwúrúju láti fa àwọn ènìyàn sí ìkànnì Paxful.
  • Lílọ́wọ́sí èyíkèyí irú àwọn ìṣe tí kò b'ófìnmu, bóyá ó nííṣe pẹ̀lú lílo ìkànnì àti àwọn ètò ìlò Paxful rẹ tàbí bẹ́ẹ̀ kò.
  • Ṣíṣẹ̀dá àwọn àkántì àlékún lóri ìkànnì Paxful tó jẹ ànfààní lára Ètò Ìbánipolówó Paxful ní èyíkèyí ọ̀nà. Àkántì ẹyọ̀kan ni a f'àyè gba ìwọ láti ní a kò sì f'àyè gbà ọ́ láti tà, yá, pín tàbí ní ìdàkejì pèsè àkántì rẹ tàbí èyíkèyí àlàyé tó ṣe pàtàkì láti wọ àkántì rẹ fún àwọn ènìyàn tàbí àwọn ǹkan ju ara rẹ lọ. Ṣíṣẹ̀dá àlàyé irọ́ fún àkántì rẹ, pípa irọ́ orílẹ-èdè abínibí rẹ tàbí pípèsè àwọn ìwé àkọsílẹ̀ ìdánimọ̀ àrékérekè ní a ṣe ní èèwọ̀.
  • Èyíkèyí ìrúfin tàbí ìtàpá sí àwọn ọ̀ranyàn rẹ láti ọwọ́ rẹ tàbí àwọn aṣojú rẹ ní abẹ́ àwọn Àdéhùn àti Àlàálẹ̀ yìí.
  • Lílo – ní irú èyíkèyí ìpolówó tàbí ìfisórí afẹ́fẹ́ mííràn tàbí ìròyìn èyíkèyí tí ọ dásílẹ́ tàbí tàn kiri tàbí ṣàkóso ní ìdàkejì – àwọn ọ̀rọ̀ “pax” tàbí “paxful” tàbí èyíkèyí òmííràn tó bá jọ wọ́n, dún bíi wọn, tàbí àwọn ọ̀rọ̀ mííràn, àwọn ààmì, tàbí àwọn orúkọ tí Paxful ríi wípé ó jọ mọ́ ààmì-òwò rẹ̀ PAXFUL ní ọ̀nà tó rú'jú.
  • Ẹ̀gàn pípa, pípa irọ́ mọ́, tàbí ìbanilórúkọjẹ́ (a) Paxful tàbí èyíkèyí lára àwọn olùdarí rẹ̀, àwọn òṣìṣẹ́, àwọn agbaṣẹ́ṣe, àwọn olùrànlọ́wọ́, tàbí àwọn aṣojú, tàbí (b) àwọn aṣàmúlò ìkànnì Paxful, pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Ètò Ìbánipolówó mííràn.
  • Lílọ́wọ́sí àwọn ìṣe tí Paxful gbàgbọ́ (ní ìfẹ́ inú àti ìdájọ́ àdáni rẹ̀) wípé ó lè fa àyẹ̀wò òfin, ìlànà, tàbí ìpẹ̀jọ́ fún un lábẹ́ àwọn òfin, tàbí àwọn ìlànà èyíkèyí orílẹ̀-èdè, ẹgbẹ́ àwọn orílẹ̀-èdè àgbáyé (pẹ̀lú European Union), tàbí sàkání òfin mííràn tàbí àjọ ìjọba pẹ̀lú, sùgbọ́n tí kò díwọ̀n sí títa tẹ́tẹ́ lọ́nà tí kò b'ófìnmu, jìbìtì, ìfowópamọ́ lọ́nà àìtọ́, tàbí àwọn ìṣe ìgbéṣùmọ̀mí.
  • Lílọ́wọ́sí èyíkèyí irú àwọn ìṣe tí kò b'ófìnmu, bóyá ó nííṣe pẹ̀lú lílo ìkànnì àti àwọn ètò ìlò Paxful rẹ tàbí bẹ́ẹ̀ kò.
  • Pèsè àlàyé èké, tí kò ṣe déédé tàbí tí ó ń ṣinilọ́nà.
  • Pèsè ìjẹ́rìísí ìdánimọ̀ àti àdírẹ́ẹ̀sì èké, tí kò ṣe déédé tàbí tí ó ń ṣinilọ́nà.
  • Ṣe ìwúrí tàbí mú kí èyíkéyì ẹnìkẹta kí ó kópa nínú èyíkéyì àwọn iṣẹ́ tí a kọ̀ léèwọ̀ lábẹ́ Abala yíí.

Àwọn Ẹ̀tọ́ Ọgbọ́n Àtinúdá

Àfi tí a bá tọ́ka ìdàkejì, gbogbo àwọn ẹ̀tọ́ ọgbọ́n àtinúdá nínú Wẹ́búsaìtì àti èyíkèyí àkóónú tí a pèsè ní ìbátan pẹ̀lú àwọn ìlò, jẹ́ ohun ìní Paxful tàbí àwọn aláṣẹ wa tàbí àwọn olùpèsè ní àwọn òfin ìní ọgbọ́n àtinúdá ń dáàbò bò. A kò fi àṣẹ kankan sílẹ̀ fún ìlò àwọn àkóónú Wẹ́búsaìtì náà. Ìwọ́ lè má tà tàbí ṣe ìyípadà àwọn ohun èlò Wẹ́búsaìtì tàbí ṣe àtúnṣe, fi hàn, ṣe ní ojútáyé, pín tàbí ní ìdàkejì lo àwọn ohun èlò náà ní èyíkèyí ọ̀nà fún ìwúlò ìta gbangba tàbí òwò. Lílò tí ìwọ́ ń lò àwọn ohun èlò náà lóri èyíkèyí wẹ́búsaìtì mííràn tàbí lóri ìlò fáìlì pínpín tàbí èyí tó jọ bẹ́ẹ̀ fún èyíkèyí ìdí ni a ti ṣe ní èèwọ̀.

Ìwọ́ lè má ṣe àdàkọ èyíkèyí ohun èlò tàbí àròkọ tó wà lóri Wẹ́búsaìtì tàbí tí o lè rí nípasẹ̀ Wẹ́búsaìtì láì sí ìgbaniláàyè wa tí a kọ. Èyíkèyí àwọn ẹ̀tọ́ tí a kò bá gbà láàyè ní kíákíá láti lo àwọn ohun èlò tó wà lóri Wẹ́búsaìtì náà jẹ́ tí Paxful ní kíkún.

Ìdíwọ̀n Layabílítì/Iyàn

Sáìtì yìí àti Ètò Ìbánipolówó ni a pèsè lóri "bó ṣe rí" àti "bó ṣe wà" fún ìfitónilétí rẹ àti ìlò láìsí èyíkèyí aṣojú tàbí ìfọwọ́sí. Dé iye tó pọ̀ jù tí òfin f'àyè gbà, a kìí ṣe èyíkèyí àwọn àtìlẹ́yìn ọjà, bóyá ní kíákíá tàbí ní àdàpè, ní ìbátan pẹ̀lú sáìtì tàbí Ètò Ìbánipolówó, pẹ̀lú sùgbọ́n tí kò dópin sí, àwọn àdàpè àwọn àtìlẹ́yìn ọjà tó dára, ṣiṣẹ́ tẹ́nilọ́rùn, ṣe déédé fún ìwúlò kan ní pàtó, àìrúfin, ìbámu, ààbò, déédé, májẹ̀mú tàbí àṣeparí tàbí èyíkèyí àtìlẹ́yìn ọjà tó jẹyọ ní ìgbà ìṣòwò tàbí ìlò tàbí òwò.

Tí àti dé iye tó pọ̀ jù tí òfin tó wúlò gbà láàyè, a kò ní dáhùn fún:

  • 1. Èyíkèyí àwọn ìpàdánù ọrọ̀-ajé (pẹ̀lú láì sí ìdópin ìpàdánù àwọn owó àpawọlé, àwọn èrè, àwọn iṣẹ́, òwò tàbí ìfowópamọ́ tí ò fọkànsī);
  • 2. Èyíkèyí ìpàdánù ojúrere tàbí ìgbayìsí;
  • 3. Àwọn ìpàdánù pàtàkì tàbí àìṣe-tààrà tàbí okùnfà, gbogbo bí ó bá ṣe wù kó ṣẹlẹ̀.

Adíyelófó àti Ìdìmú Aìnípalára

Ìwọ́ gbà láti mú Paxful, Inc. bíi èyí tí kò ní ìpalára (ati ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn olórí wa, àwọn olùdarí, àwọn ọmọ ẹgbẹ́, àwọn òṣìṣẹ́, àwọn aṣojú àti àwọn Abánipolówó) lọ́wọ́ èyíkèyí ẹ̀tọ́, ìbéèrè, ìṣe, ìbàjẹ́, ìpàdánù, ìdíyelé tàbí ìnáwó, pẹ̀lú láìsí ìdiwọ̀n àwọn owósan òfin tó tọ́, tí ó jẹyọ tàbí jọ mọ́: lílo rẹ, tàbí ìhùwàsí ní àsopọ̀ pẹ̀lú, Ètò Ìbánipolówó wa; tàbí ìtàpá sí àwọn Àdéhùn àti Àlàálẹ̀ wọ̀nyí. Ní àfikún, o gbà láti dáhùn ní kíkún fún (àti kí o ṣọ́ wa ní kíkún lọ́wọ) gbogbo àwọn ẹ̀tọ́, layabílítì, àwọn ìbàjẹ́, àwọn àdánù, àwọn ìdíyelé àti àwọn ìnáwó, pẹ̀lú àwọn owósan òfin, tí a jìya rẹ̀ tó jẹyọ láti tàbí ní ìbátan pẹ̀lú èyíkèyí ìtàpá sí òfin àwọn Àdéhùn àti Àlàálẹ̀ nípasẹ̀ rẹ tàbí àwọn gbèsè mííràn tó wáyé nípasẹ̀ wa tó jẹyọ nípa lílo áwọn ètò ìlò náà àti Ètò Ìbánipolówó rẹ, tàbí lílò nípasẹ̀ ènìyàn mííràn tó ń lo àwọn ètò ìlò náà nípa lílo àkántì aṣàmúlò rẹ, ẹ̀rọ tàbí àkántì ìráyè wọlé sí orí ayélujára; tàbí ìtàpá rẹ sí èyíkèyí òfin tàbí àwọn ẹ̀tọ́ ti èyíkèyí ẹnìkẹta.

Gbogboògbò

Àwọn Àdéhùn àti Àlàálẹ̀ yìí àti ìlò Wẹ́búsaìtì àti Ètò Ìbánipolówó rẹ ní yóò wà ní ìṣàkóso ní ìbámu pẹ̀lú Òfin Orílẹ̀-èdè United States. Èyíkèyí àríyànjiyàn tó bá jẹyọ pẹ̀lú àwọn Àdéhùn àti Àlàálẹ̀ wọ̀nyìí tàbí ìlò Wẹ́búsaìtì tàbí Ètò Ìbánipolówó rẹ ni yóò jẹ́ yíyanjú ní àwọn ilé-ẹjọ́ Orílẹ̀-èdè United States. Ohunkóhun nínú àwọn Àdéhùn àti Àlàálẹ̀ yìí ní ìwọ kò ní rí bíi ìpalára fún àwọn ẹ̀tọ́ rẹ ní abẹ́ òfin Orílẹ̀-èdè United States. Tí èyíkèyí apákan ti Àdéhùn àti Àlàálẹ̀ yíí bá jẹ́ dídìmú nípasẹ̀ èyíkèyí ilé-ẹjọ́ United States láti jẹ aláìtọ̀nà tàbí àìlágbára ní odidi tàbí ní apákan, ìtọ̀nà tàbí kíkàn-án-nípá àwọn apákan àwọn àdéhùn àti àlàálẹ̀ wọ̀nyí àti àwọn ipò kìí yóò ní ipa. Èyíkèyí àwọn àkọlé tí ó wà nínú Àdéhùn àti Àlàálẹ̀ yíí wà fún àwọn ìdí àlàyé nìkan àti pé kìí ṣe àwọn ìpèsè tí o ṣeé kàn-án-nípá fún Àdéhùn àti Àlàálẹ̀ yíí.