Káàbọ̀ sí Owó Afènìyàn-ṣọrọ̀

Paxful ń yí ayé ìṣúná padà. Ní ọdún márùn péré, a ti di ọkan nínú àwọn tí ó ń léwájú ní àwọn ibi ìtajà ẹnìkan-sí-ẹnìkejì ti bitcoin tí àìmọye mílíọnù kákìri àgbáyé ń lò. Àti pé aṣẹ̀ṣẹ̀ n bẹ̀rẹ̀ ni.

Àwọn olùdásílẹ̀ wa

Paxful bẹrẹ pẹlú èróńgbà tí ó rọrùn: láti ṣe ìrólágbára fún bílíọ̀nù mẹrin tí a ti gbàgbé pé kò ní banki àti tí kò lo banki déédé, nítorínáà wọn ní ìṣàkóso ti owó wọn ní ọnà tí wọn kò tíì rí tẹlẹ.

Ray Youssef

Ray Youssef, Alákóso

Àjòjì kan láti Egypt tí o dàgbà ní àárín New York, Ray ti ní ìfẹ nígbàgbogbo fún ìrànlọwọ àwọn mííràn. Ó lá àlá kan nípa àgbáyé níbití ìṣúná owó-wíwọlé wà fún gbogbo ènìyàn àti pé ìmọràn yẹn farahàn bí Paxful.

Àwọn kókó wa

A ń gbé àti ṣiṣẹ nípasẹ àwọn kókó tí ó rọrùn mẹta láti ṣe ìtọsọnà wa lórí ìbéèrè ọ̀pọ̀ yanturu wa.

Kókó àmójútó Paxful Kókó àmójútó Paxful

Jẹ Akíkanjú

Ní Paxful, a lo àwọn ipá tí ó ju ti èèyàn lọ láti mú kí iṣẹ parí. A ṣiṣẹ yika aago láti pèsè àwọn aṣàmúlò wa pẹlú ohun tí wọn ti ń lálá rí. À ń sọ ohun tí kò ṣèé ṣé di òtítọ láti yí ìgbésí ayé àwọn ọkẹ àìmọye padà káàkírí àgbáyé.

Ṣàgbékalẹ̀ fún Ènìyàn

Nígbàtí a bá ṣe àwọn ìpinnu ní Paxful, a ronú nípa ènìyàn — kìì ṣe àwọn èrè. A ń lọ sí àwọn ààyè tí ìyókú àgbáyé ti fojú fò àti gbàgbé. A ń ṣe ìrànlọwọ fún àwọn ìdílé láti ṣe rere, kọ àwọn ilé-ìwé, àti ìmú àwọn aṣàmúlò wà láàyè láti di ọgá ara wọn.

Wà ni àsopọ̀ pẹ̀lú ìgboro

A tẹtísí agbègbè wa 24/7 ní Paxful. A kò sí ní àwọn ilé-ọrun pẹlú “àwọn ìpèlé” —a wà ní ìgboro pẹlú àwọn ènìyàn. A ń sọrọ nígbàgbogbo pẹlú àwọn aṣàmúlò wa, ń bèèrè lọwọ wọn fún ìjábọ̀ wọn, àti ṣíṣẹdá ńkan pàápàá dára jùlọ.

Rà àti tà Bitcoin àti Tether lórí Paxful

Ọjà wa

Paxful ń ṣe ìyípadà ọnà tí àgbáyé ń gbà gbé owó àti ìtẹ́wọ́gbà kírípítò - gbígbà láàyè àwọn ìfowóránṣẹ́ pẹlú ẹnikẹni, níbikíbi, nígbàkúgbà.

Kò sí àkántì báǹkì? Kòsí wàhálà. A ní àwọn ìlànà ìsanwó tò ju 300 lọ láti yàn, ṣíṣe ní ìrọrùn fún ọ láti gbé owó rẹ ní ọnà tí o fẹ.

Tẹkinọ́lọ́jì afènìyàn-ṣọrọ̀

Paxful jẹ ẹnìkan-sí-ẹnìkejì pátápátá, èyítí ó túmọ sí pé àwọn aṣàmúlò wa ṣòwò pẹlú àwọn ènìyàn gidi-ọnà tí a pinnu bitcoin láti lò.

Wálẹ́ẹ̀tì kírípítò ọ̀fẹ́

Gbẹkẹle, ó rọrùn láti lò, àti pé kò ná ọ ní éépìnì. wálẹ́ẹ̀tì onídíjítà wa fún gbogbo ènìyàn ní ààyè àìléwu láti tọjú ọrọ wọn - láìbìkítà tani ọ́ jẹ tàbí ibití o ti wá.

Ní ààbò

Ààbò àti ìdáàbòbò ní àwọn okùnfà tí ó ṣe pàtàkì jùlọ tí a bá ń sọ nípa owó rẹ. Gbogbo àwọn òwò lórí Paxful ní ààbò nípasẹ iṣẹ́ ààbò ẹsíkírò wa láti ṣe ìṣèdúró àlàáfíà ti ọkàn.

#BuiltwithBitcoin

Ní Paxful, a gbàgbọ pé Bitcoin ni ọjọ iwájú àti ọkọ ayọkẹlẹ fún ìyípadà. Gbékalẹ̀ pẹ̀lú Bitcoin jẹ ìpilẹṣẹ wa láti pèsè àwọn àyè, mú àwọn ìgbésí ayé dára, àti jẹ kí ayé jẹ ààyè tí ó dára jùlọ fún àwọn agbègbè tí ó nílò rẹ jùlọ, ní lílo Bitcoin.

Ibi tí a ńlọ? Láti kọ àwọn ilé-ìwé 100, àwọn ohun èlò omi, àti àwọn àgbékalẹ̀ iṣẹ́-ọwọ tí Bitcoin ṣe agbátẹrù owónàá rẹ. Lọwọlọwọ à ń kọ ilé-ìwé kẹrin wa àti pé a sì fẹ kọ 96 síi!

Tí a kọ pẹlú Bitcoin tún ṣe ìrànlọwọ pẹlú ìdẹ̀rùn COVID-19 ní Áfíríkà-pẹlú àwọn ẹbùn onínúrere láti ọdọ àwọn olumulo wa àti àwọn ọrẹ a ní ànfàní láti pèsè oúńjẹ, àwọn ọṣẹ ìfọwọ, àti àwọn ohun èlò ààbò mííràn sí àwọn tí ó nílò.

Darapọ̀ mọ́ wà! Jẹ ki a gbìmọ̀ jọ yí ìgbé ayé padà.

Kọ ẹkọ síwájú síi
Alákóso Paxful Ray Youseff
Alákóso Paxful Ray Youseff
Darapọ̀ mọ́ Paxful

Ẹgbẹ́ wa

4

Àwọn ọ́fíìsì wa káríayé

200+

Àwọn òṣìṣẹ tí ó fẹ láti ṣe àgbáyé ní àyè tí ó dára jùlọ

21

Àwọn èdè tí a ń sọ ní àwọn ọ́fíìsì àgbáyé wa

1

Èróńgbà láti kọ àgbàyè pẹlú ìráyè sí owó dọ́gba fún gbogbo ènìyàn

Darapọ̀ mọ́ Paxful Ọ́fíìsì Paxful ní Talinn
Ọ́fíìsì Paxful ní Talinn Ọ́fíìsì Paxful ní New York
Ọ́fíìsì Paxful ní Manila Paxful ni Hongkong

Àwọn Olùbásọ̀rọ̀ Òwò

Tí ìwọ́ bá ní ọ̀ràn àtìlẹ́yìn tàbí o fẹ́ fún wa ní ìjábọ̀ nípa bí a ṣe lè ṣe ìmúdára síi àwọn ọjà wa, a yóò nífẹ̀ẹ́ láti gbọ́ síi nípa rẹ̀ . Ṣùgbọ́n tí ìwọ́ bá fẹ́ kàn sí Paxful nípa àwọn ìbéèrè tó níí ṣe pẹ̀lú ìṣòwò mííràn, a tún wà nílẹ̀ nípasẹ̀ àwọn ìkànnì Mííràn.

Ìròyìn àti Ìtajà

Ṣe ìrànlọ́wọ́ láti tan ọ̀rọ̀ náà káàkiri nípa Paxful nípasẹ ètò ìfiléde ati ìtajà. Kàn sí wa fún àwọn ìbéèrè ní [email protected].&Lrm;

Bug Bounty

Ètò Bug Bounty fún ọ ní àyè láti jẹ èrè fún ìdámò àwọn ọ̀ran ìmọ̀-ẹ̀rọ. Fi wọ́n sùn ní [email protected] . Àlàyé síi níbí .&Lrm;

Àwọn Àkántì Ilé-iṣẹ́

Láti forúkọ àkántì ilé-iṣẹ́ sílẹ̀ fún ìdókoòwò àwọn ìṣòwò lóri Paxful, ìwọ́ lè fi ímeèlì ránṣẹ́ sí [email protected]. Àlàyé síi níbí.‎

Àwọn Ìtajà àti Àwọn Àjọṣepọ̀

Láti ṣe ìbéèrè nípa dídi alábáṣepọ̀. Jẹ́ kí á mọ̀ tí o bá ní ìfẹ́ sí àṣepọ̀ pẹ̀lú wa nípasè fífi ímeèlì ránṣẹ́ sí [email protected].‎

Darapọ̀ mọ́ Paxful
Jẹ ki a gbìmọ̀ ṣàgbékalẹ̀ ọjọ́ iwájú
Darapọ̀ mọ́ Ìgbìmọ̀ wa

Ṣẹdá àkántì Paxful tìrẹ kí o bọ sínú ayé kírípítò.